Biyi Otegbeye ekun oko Dapo, da nnkan ru mo APC loju. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 16 March 2023

Biyi Otegbeye ekun oko Dapo, da nnkan ru mo APC loju.
Bi won ba ni ta ni wahala de ba ju lakooko yii ti okan e ko bale bayii, Gomina Dapo Abiodun ni,nitori idaamu ti Biyi Otegbeye ko ba a ki i se kekere, o si dabi eni pe ara ti n ro fun oun ati egbe oselu APC, nibi ti Ibo Satide, n lo lojo Satide, ose yii.

Idi abajo ni pe okan okunrin naa ko bale mo, nitori ko fee nigbagbo ninu awon eeyan to n tele paapaa julo ni ekun Yewa- Awori, ti won yari pe egbe ADC lawon yoo se, awon lo fe ki anfaani yii ko fo won ru.

Ariwo ti won n pa ni pe odun 2023 yii lawon fee, ki i se 2027, nitori ko si eni to le so nnkan ti yoo sele bayii.

Iwadii tie fi ye wa pe awon gomina tele kan nipinle Ogun, naa ti n fowosowopo lati ri i pe Dapo Abiodun lule ninu Ibo to n bo, ta a si n gbo pe ADC, ni won sise fun.

Bee loro se ri fáwọn osise ijoba ipinle naa ti won so pe Ibo awon lawon yoo fi so fun Dapo Abiodun pe ijoba odun merin to lo ti to ge, ko pada si Iperu to ti wa.

Laipe yii naa si ni Biyi Otegbeye, oludije ipo gomina pariwo sita pe akoko ti won wa yii, ki onikaluku gbe agbelebu e, nitori oun lo le sise tabi juwo sile fegbe oselu kankan ki won je kawon pade lori papa pelu idaniloju pe yoo jawe olubori ninu Ibo naa.

Eni to ba ri Dapo Abiodun ti oju e pon lakooko yii, e ma ba wi, Otegbeye to fee fi ona Ile han an, lo ko wahala ba a.

No comments:

Post a Comment

Pages