Ibo Gomina:Emi o ni lokan lati juwo sile fun Ladi Adebutu PDP- Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 15 March 2023

Ibo Gomina:Emi o ni lokan lati juwo sile fun Ladi Adebutu PDP- Otegbeye



Oludije fun ipo gomina labe egbe oselu ADC nipinle Ogun, Agbejoro Biyi Otegbeye, ti so pe iro to jinna si ooto ni pe oun ti gba lati juwo sile fun Onarebu Ladi Adebutu,tegbe oselu PDP, ti won jo dupo gomina ninu Ibo ti yoo waye lojo Satide, ose yii.

Okunrin naa soro yii lakooko to n ba egbe awon oniroyin tipinle naa forojomitoro oro, eyi to waye ni iwe iroyin niluu Abeokuta.

O so pe oro to wa nile yii ti di olomu da omu Iya e gbe, ki onikaluku si da agbelebu tie gbe.

O ni ki egbe oselu to ba to gbangba sun loye ko pade lori papa. Bakan naa lo so pe oun lo rii ro pe awon oba alaye fonte lu oludije kan.

Otegbeye so pe eyi to se pataki ni pe ero ti won yoo lo ti won pe ni BVAN, ko mo nnkan to n je onte bi ko se kaadi idibo tawon eeyan yoo lo lojo idibo, iyen PVC.

O salaye siwaju pe, Bi Seneto Ibikunle Amosun se fonte lu mi, to satileyin fun mi, iyen ko so pe ki n lo sun, mo ni lati sise kaakiri lati je kawon araalu mo nipa erongba mi, iyen fáwọn ti yoo dibo"

"Pelupelu pe awon oba alaye so nita gbangba iyen ko ni ki won so o di gomina"

Bee ni oludije gomina labe egbe oselu ADC naa tun gboriyin fun Seneto Ibikunle Amosun lori atileyin nla to n ri gba.Pelu ileri pe oun ko mi juwo sile fenikeni, nitori oun ti gbaradi, o si da oun loju pe bi ogo ti n je ti Olorun, oun yoo jawe olubori.

O so pe nibi tawon ba ise de, o ti ju kawon se asepo pelu egbe oselu mii-in. O waa lo akoko naa lati ke si awon eeyan ipinle Ogun lati fi Ibo won gbe oun wole lojo Satide ose yii.

No comments:

Post a Comment

Pages