Bi ala lọrọ naa si n jẹ fun ẹgbẹ oṣelu APC, nipinlẹ Ogun, koda wọn ko tii gba ara wọn gbọ, ko si si nnkan to fa a bi ko ṣe pe wọn lero pe iru nnkan bẹẹ ko le waye tabi ṣee ṣe ninu ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ogun.
Ohun to si n jẹ kayeefi fun wọn ni bi wọn ṣe gbọ pe Ọnarebu Ladi Adebutu ati Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi ṣe pari aawọ to wa laarin wọn, ti wọn si ti gba lati jọ ṣiṣẹ pọ ki wọn fi le gba ijọba lọwọ APC, ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ kejidinlogun, oṣu yii, iyẹn Satide to n bọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nibi eto ori redio tawọn apapọ kan ṣe niluu Abẹokuta, ti wọn ti gba Ṣẹgun Ṣowumi lalejo nipa imurasilẹ fun ibo to n bọ. Bi ọkunrin yii ṣe n sọrọ lọwọ, lojiji ni ipe Ọnarebu Ladi Adebutu, ti wọle, ti wọn si jọ sọrọ bi alafia yoo ṣe jọba, ti wọn yoo si ṣẹgun abẹle to wa laarin, ki wọn le ri ogun ita ṣẹ.
Pẹlu idunnu ni wọn sọ pe Ṣowumi fi gba to si mu da Ladi loju pe oun yoo pe sibi ayẹyẹ nibi ti gbogbo wọn yoo ti jọ jiroro nipa bi wọn yoo ṣe jagunmolu ninu ibo to n bọ ọhun. Ayẹyẹ yii lo waye nile ọkunrin naa to wa niluu Abẹokuta, nibi ti gbogbo awọn alatilẹyin awọn mejeeji ti pade to fi mọ awọn oloye ẹgbẹ naa.
Pẹlu idunnu ni Ọnarebu Ladi Adebutu fi sọ pe ko si wahala Kankan mọ laarin oun ati Ṣẹgun Ṣowunmi, ti wọn jọ dije dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP mọ, ati pe nnkan to wa niwaju oun bayii, ni bi wọn yoo ṣe gbajọba lọwọ Dapọ Abiọdun.
Bẹẹ lo tun sọ pe oun ko tiẹ ri bawọn ọmọ ẹyin Buruji Kashamu, ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ lọọ darapọ mọ APC. O sọ pe awọn agbọyisọyi lo da wahala silẹ laarin oun ati Ṣẹgun Ṣowunmi, amọ ti gbogbo ẹ ti lọ si okun igbagbe.
O ni elebi lawọn to fẹgbẹ naa silẹ lọọ darapọ mọ APC, ko si ifẹ ẹgbẹ lọkan wọn, bi wọn ṣe lọ yẹn lo ni yoo tun jẹ ki ẹgbẹ naa tun tẹsiwaju.Bẹẹ lo rọ awọn ọmọ ẹyin Ṣowunmi lati gba ipade alaafia naaa laye, to ni ki wọn ma ṣe fi ẹgbẹ silẹ..
No comments:
Post a Comment