Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun, INEC, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ ti wọn n gbe kaakiri pe awọn ti yọ orukọ Ọnarebu Ladi Adebutu, ti ẹgbẹ oṣelu PDP, kuro ninu awọn oludije ti yoo kopa nibi ibo ti yoo waye lọjọ Satide, Abamẹta, ọsẹ yii.
Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sita, to fi tako iroyin kan tawọn kan gbe jade lori ẹrọ ayelujara pe PDP, ko ni oludije kankan fun ibo gomina to n bọ ọhun, wọn ni ibi ti wọn ti ri ni ko ye awọn.
Ọgbẹni Niyi Ijalaye, to jẹ ọga agba fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ogun naa sọ pe ko si nnkan to jọ bẹẹ ati pe ibi ti wọn ti n gbọ igbọkugbọ ko ye awọn, nitori pe titi di akoko to n sọrọ yii, Ladi Adebutu, si ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọkunrin naa sọ pe " Ahesọ ọrọ lasan n, ko tiẹ waye rara, titi di bi mo ṣe n sọrọ yii Adebutu ṣi ni oludije fun ipo gomina, mo waa fi akoko yii rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ogun, ki wọn ma ṣe gba a gbọ’’
A gbọ pe awọn kan ti ẹru n ba ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ni wọn n sọ isọkusọ lati fi tan awọn araalu jẹ.
No comments:
Post a Comment