Bo tilẹ jẹ pe ọsẹ to kọja yii lo yẹ ki ibo gomina atawọn aṣofin waye kaakiri orileede yii, ṣugbọn ti ajọ to n ṣeto idibo INEC, sun di ọjọ Satide, ọsẹ yii, Ni bayii awọn ọmọ Yewa-Awori ti sọ pe akoko tawọn yoo di gomina lawọn wa yii, awọn ko le duro di ọdun 2027.
Ọrọ yii jade lọsẹ to kọja, nigba ti Sẹnetọ Ibikunle Amosun, to jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, ṣaaju oludije gomina fẹgbẹ ADC, Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ṣe ipolongo lọ siluu Ilaro, nibẹ ni ọrọ ti bọ, tawọn Yewa-Awori, ti pariwo pe awọn ti ko fẹ ilọsiwaju Yewa-Awori, ni wọn tun le sọ anfaani ti wọn ni lakooko yii nu.
Ninu ọrọ tawọn eeyan sọ lọjọ naa, ni wọn ti sọ pe lati nnkan bi ọdun mẹtadinlaadọta, ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, gbogbo agbara ni wọn ti sa lati rii pe ẹni to wa lati igun naa di gomina, to si n jẹ pabo nitori aini isọkan lati fẹnu ko lori oludije kan, iya ẹ lo si n jẹ wọn titi di oni.
Wọn ni bawo ni ẹni to ero rere fun ilẹ naa yoo se tun wa sọ pe lakooko ti wọn ni oludije kan soso lati ọdọ wọn to n dije fun ipo ọhun, wọn ko waa ni fọwọsowọpọ pẹlu ẹ. Gẹgẹ bi ọrọ Tolu Ọdẹbiyi, to jẹ aṣoju wọn nile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja, iyẹn Ogun Wes, lo ti sọ pe akoko ti to lati fi ohun sọkan lati tako awọn ti wọn ṣe imọtara ẹni oṣelu lati gba ogo pada wa si ilẹ Yewa Awori.
O sọ pe idunnu ni yoo jẹ foun tawọn ba pe pamọ pọ dibo yan Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ninu ibo to n bọ lọjọ Satide, ọsẹ yii. O ni inu baba oun, Jonathan Ọdẹbiyi atawọn agba bii Alagba Tunji Ọtẹgbẹyẹ, Tunji Olurin, Sẹnetọ Afọlabi Ọlabimtan, YAB Ọlatunji, Bọlarinwa Abioro atawọn yooku ti wọn ti tiraka ki wọn to gbesẹ yoo dun ni ọrun.
Ọdẹbiyi sọ pe iṣẹ ti Ọlọrun ti pari ni ibo to n bọ naa amọ awọn gbọdọ sa fawọn onimọ-tara-ẹni ti wọn ṣiṣẹ tako wọn, tawọn si mọ pe oju yoo ti wọn, lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii. Bakan naa ni Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo ati Ọnarebu Jimoh Olaifa, to n ṣoju agbegbe ẹkun Yewa North ati Imẹkọ-Afọn, nile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, naa sọ pe dandan ni ki wọn fi imọsọkan lati jẹ ki Yewa-Awori, di gomina.
Alaaji Surajudeen Olusesi, agba oṣelu lati Ọta, sọ pe awọn eeyan Awori, ti ṣetan lati ṣiṣẹ fun Ọtẹgbẹyẹ. Nigba toun naa sọrọ nibi ipolongo ọhun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, to n ṣoju ẹkun agbegbe Ogun Central, sọ pe idunnu lo jẹ pe ipinlẹ Ogun, pese awọn eeysn gidi, to koju oṣuwọn bi Ọtẹgbẹyẹ, lati dije fun ipo gomina.
O sọ pe ‘’Ṣe ẹ ri gbogbo awọn eeyan ti wọn sọ pe Yewa-Awori, ko ti ni ẹni to le ṣaaju wọn ko jẹ olootọ rara. O ni agbegbe Ogun-West, ti pese awọn eeyan nla bii Sẹnetọ Jonathan Odebiyi, Ayọdeji Ọtẹgbọla, Iyabọde Aniṣulowo, Kọla Bajọmọ, Bọlarinwa Abioro,Ọgagun Tunji Olurin, atawọn yooku.
" Lakooko, ninu ibo to n bọ yii, ọwọ ẹyin eeyanYewa-Awori lo wa, ẹ gbọdọ ja fun ara yin ati fun iran to n bọ, ẹ lo kaadi alalopẹ yin PVC.lati fi dibo fun ọmọ yin, Biyi Ọtẹgbẹyẹ, lo si kun oju oṣuwọn ju laarin awọn ti wọn jọ n dije fun ipo gomina''.
No comments:
Post a Comment