Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu to n bọ, ni ayẹyẹ onibẹta kan yoo waye niluu Eko, eyi ti yoo min titi. Arabinrin Hannah Babatunde Adenikẹ, tọpọ awọn ololufẹ ẹ mọ si Hanny Fingers, to jẹ olorin ẹmi, sọrọsọrọ ori tẹlifiṣan, lo fẹẹ da silẹ fawọn tiẹ lọjọ naa.
Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn fi sọwọ si wa, ọjọ naa ni akọni obinrin naa yoo ṣe ifilọlẹ kasẹẹti orin tuntun ẹ keji, to pe ni ‘Oluwakorede’, bẹẹ naa ni yoo tun fi awọọdu da awọn eeyan lọla, pambabari ẹ ni ayẹyẹ ogoji ọdun to dele aye.
Ojule kẹtadinlogun, Ogundipẹ, Oshoogun, Alapẹrẹ, Ketu, ni eto ọhun yoo ti waye bẹrẹ ni deede aago kan ọsan.
Ninu ọrọ ẹ, Arabinrin Hanny Fingers, sọ pe, ‘ Mo fẹẹ lo akoko yii lati pe awọn eyan ki wọn wa pọn mi le lọjọ naa,meyi ti yoo jẹ ọjọ manigbagbe si rere ninu igbe aye onikaluku wa, ọpọ awọn eeyan pataki lawujọ ni mo maa fi ami ẹyẹ da lọla, bẹẹ naa ni maa tun fi ọjọ naa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ayẹyẹ ọjọọbi pe mo di ẹni ọgoji ọdun laye’’
No comments:
Post a Comment