Seneto Solomon Olalekan Adeola, to sese jawe olubori gege asofin agba fun ekun Ogun West ti so pe pelu awon ise takuntakun ti Gomina Dapo Abiodun ti se nipinle Ogun iyen gan an ti to fáwọn araalu lati dibo fun un ni eleekeji.
Seneto soro naa lakooko to n se ipade po pelu awon agbe ti won to igba ti won je Agbe fun ilosiwaju ati egbe Asiwaju agbe, eyi ti Dokita Angel Adelaja Kuye, to je oluranlowo pataki fun Gomina lori eto ogbin.
Nibe lo ti fun egbe alajeseku awon agbe naa ni milionu lona ogun naira gege owooya fun won. O so pe fun igba akoko, Gomina Dapo Abiodun si awon ise akanse lawon ijoba ibile to wa nipinle Ogun to ni o yato sawon isakoso to ti kọja tele.
O fikun oro e pe ki fee si apa ibi ti ko nawo idagbasoke de nii eto eko, ilera ati imayederun.
Bee lo tun lo akoko naa leekansi lori bi won se fi Ibo won gbe oun wole. O waa ro won pelu bi won se se yii bee naa ni ki won se fun Gomina Dapo Abiodun fun Ibo to n bo lojo Satide, ose yii.
Bakan naa lo tun seleri fáwọn agbe naa pe oun yoo ri pe won je anfaani lopo yanturu fáwọn eto lorisirisi nigba toun ba bere ise gege asoju won nile igbimo asofin agba.
Ko to to akoko yii ni Dokita Adelaja Kuye ti so pe pataki ipade won Seneto Adeola ni pe bo se satileyin fáwọn agbe ni Eko, gege bi asofin fun ekun Lagos West bee naa ki se fáwọn paapaa iranlowo lati of ijoba apapo.
No comments:
Post a Comment