Loootọ lawọn fayawọ ko jawọ ṣugbọn awa naa ko gboju bọrọ fun wọn- Bamidele Makinde - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 6 April 2023

Loootọ lawọn fayawọ ko jawọ ṣugbọn awa naa ko gboju bọrọ fun wọn- Bamidele Makinde



Ọga agba fun ẹṣọ aṣobode nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Bamidele Makinde, ti sọ pe loootọ lawọn fayawọ ko fẹẹ jawọ ninu ki ko ẹru ofin wọlu ṣugbọn inu oun dun pe  ṣe ni wọn ba awọn naa nibẹ, nitori bi wọn ṣe n foju wọn ri mabo, ti wọn si n gba awọn ẹru ti ko ba ofin mu, ti wọn ko wọlu.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi ipade oniroyin ti wọn ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii niluu Abẹokuta, lakooko to jiṣẹ irinju wọn ti saa akọkọ ninu ọdun yii. O sọ pe bi awọn ba foju inu wo owo tawọn ko jọ fun saa naa to miliọnu mẹrinlelogoji, ẹgbẹrun lọna ọgọrin le marundinlọgọta ati aadọta naira, iyẹn N44,857,053.50, bi wọn ba si ni kawọn ṣe agbeyẹwo ẹ si ti ọdun to kọja, miliọnu marun-un,ẹgbẹrun marun le mejila naira lo fi juu lọ. Bẹẹ lo sọ pe ileeṣẹ ṣiṣẹ takuntakun lati ṣagbega okoowo lọna to fi mu owo wale ws si orileede yii.



Bamidele tun fikun ninu ọrọ ẹ pe gbogbo awọn nnkan tawọn gba lọwọ awọn fayawọ loriṣiriṣi laarin oṣu mẹta akọkọ naa jẹ ọgọsan o le ẹyọ kan iyẹn 181.Lara awọn nnkan to ni awọn ri gba ọhun ni ẹgbẹrun mejila ati ẹgbẹta le mẹwaa apo irẹsi, to jẹ oni kilo aadọta ati kilo mẹẹdọgbọn,ti tirela mọkalelogun ko, ti wọn si gba wọn pẹlu tirela wọn.

Bakan naa lo ni awọn tun gba iresi Chineese to jẹ ẹẹdẹgbẹta le ni ogoji, ile itaja kan to wa ni Ṣagamu, ti wọn ko wọn si lo ni aṣiiri wọn ti tu, ti wọn ti lọ ko wọn iyẹn lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹta ọdun yii. O wa lo akoko naa lati kilọ fawọn ọmọ orileede yii lati sọra fawọn nnkan ti yoo maa ko ba ilera wọn.



Awọn nnkan mii-in ti wọn tun gba ni pali siga to le ni ẹgbẹrun kan ati irinwo to jẹ ti Chinese yii naa, awọn yooku ni awọn aṣọ awọku, bata. Taya, ipara, igbo atawọn nnkan mii-in. Bẹẹ lo ni gbogbo igbo tawọn gba lawọn ti n gbe igbesẹ lati gbe fun ọga awọn to n gbogun ti oogun oloro, NDLEA, nipinlẹ Ogun, iyẹn CN Ibiba Odili.

 Ọga aṣobode tun ṣalaye pe ileeṣẹ wọn ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹka alaabo yooku, to si tun jẹ pe ajọṣepọ wọn danmọran paapaa julọ awọn to n gbe ni agbegbe ati igberiko, eyi to jẹ ki iyatọ gedegbe maa deba fayawọ ju ti atẹyinwa lọ.

Bẹẹ naa lo wa gboriyin fawọn ọmọọṣẹ fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati doju ija kọ awọn onifayawọ ti wọn kọ, ti wọn ko fẹẹ jawọ, bakan naa lo tun gba wọn nimọran lati ma ṣe kaarẹ lori iṣẹ ti wọn yan laayo yii.

O waa pari ọrọ ẹ nipa gbigbe oriyin fun ọga wọn patapata lorileede yii, atawọn ti wọn jọ n ṣakoso lori akitiyan wọn lati jẹ ki alaafia jọba.  O tun lo akoko naa lati ranṣẹ ọdun ti isita ati awẹ to n lọ lọwọ fawọn kristẹẹni atawọn musulumi gbogbo lorileede yii.

 

No comments:

Post a Comment

Pages