Idagbasoke to ti lo seyin ni ADC yoo da pada nipinle Ogun- Ibikunle Amosun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 2 March 2023

Idagbasoke to ti lo seyin ni ADC yoo da pada nipinle Ogun- Ibikunle Amosun



Gomina tele nipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun, ti mu day gbogbo awon eeyan ipinle Ogun loju pe gbogbo nnkan to le je ki idagbasoke tubo ba ipinle Ogun, mi oludije gomina labe egbe oselu ADC, Agbejoro Biyi Otegbeye ni, ti yoo si se ti won ba le dibo yan gege bi gomina ninu Ibo to n bo lose to n bo yii.

Gomina tele naa soro yii lakooko to n bawon awon eeyan Ota, soro fun ti ipolongo to n lo lowo naa, O so pe Otegbeye kun oju osuwon lati da gbogbo ifaseyin tijoba to wa lode yii ti mu ba awon idagbasoke soke ipinle naa pada.

O fikun oro e pe ka ni ijoba to wa lode yii ba nigbagbo ninu itesiwaju idagbasoke ni, ipinle yii ki ba tun ti goke ju bayii lo.

Amosun tun so pe pelu gbogbo nnkan toun ri yii lo je ki oun jade sita, nitori awon gbodo pada si ori awon idagbasoke ye

O salaye siwaju pe laarin odun 2011 si 2019, ijoba oun sagbekale ipinle Ogun to se e dun wo loju,opo idagbasoke to se mu yangan lawon mu wa, sugbon o se ni laaanu pe gbogbo e no Dapo Abiodun mu pada wa sile.
Amosun ni,"A ko fe ki iru iru awon nnkan bee wa subu patapata, lasiko yii ko tie wa si iru mo, a se oju ona onila meds pelu ero pe lati mu idagbasoke ba ojo iwaju "

"Enikan kan se, o so o di meji, se opolo wa ninu yen bi, a o gbodo pada seyin ninu idagbasoke, nitori e ni mo se dide lati pe yin lati jade dibo lojo kokanla, osu yii, fun Agbejoro Biyi Otegbeye,ti egbe oselu ADC, gege bi gomina ipinle Ogun."

"Ni ojo naa, mo fe ki e se suuru,ki e duro titi ti won yoo fi ka Ibo yin,e ma fáwọn toogi laye lati ji Ibo gbe".

Amosun waa sapejuwe Otegbeye gege bi eni to loruko to si ni iriri pupo, to tun waa je agba agbejoro, to mo bo se le sakoso ipinle, to si ti kopa ribiribi fun idagbasoke lawujo.

Ninu oro Biyi Otegbeye lo ti mu da gbogbo eeyan ipinle Ogun loju pe ise rere to se e toka si ti adari won iyen Amosun ti se loun naa yoo tele.



No comments:

Post a Comment

Pages