Gbadebọ ko juwọ silẹ fẹnikẹni oun ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Labour ipinlẹ Eko- Dayọ Ekong - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 March 2023

Gbadebọ ko juwọ silẹ fẹnikẹni oun ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Labour ipinlẹ Eko- Dayọ Ekong 

Pasitọ Dayọ Ekong, alaga fẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko, ti sọ pe ahesọ lasan ni ọrọ kan to n ja nigboro pe Gbadebọ Rhodes- Vivour, to jẹ oludije gomina fẹgbẹ naa ninu ibo to n bọ, ti juwọ silẹ fun ipo ọhun, o ni irọ to jina si ootọ ni.

 

Ninu atẹjade ti obinrin naa fọwọ si nirọlẹ yii lo ti sọ pe titi di akoko toun si n sọrọ yii, oludije awọn ọhun yoo kopa nibi ibo ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu yii, iyẹn ọjọ Satide to n bọ.

 

O sọ pe ko si nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ to le mu ki Gbadebọ juwọ silẹ fun ipo ọhun, nitori awọn ni ipinnu pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, ọkunrin naa ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ yii.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ko si awawi kankan ninu ọrọ yii nitori pe Gbadebọ ti wa ni imurasilẹ, to si ti ṣetan lati dije ninu ibo to n bọ gẹgẹ bi gomina tuntun fun ipinlẹ Eko.

 

Alaga ẹgbẹ naa wa rọ gbogbo ọmọ  ẹgbẹ oṣelu Labour tipinlẹ Eko, lati ma ṣe tẹti si ahesọ ọrọ kankan, nitori awọn ti wọn fẹẹ ta ara wọn danu, wọn ki I ṣe ojulowo ọmọ ẹgbẹ naa, wọn ko si ni ero rere fẹgbẹ ọhun.

 

 O waa sọ pẹlu idaniloju pe Gbadebọ ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ yii, ati pe bi awọn ṣe ṣe lakooko ibo aarẹ tawọn bori bẹẹ gẹlẹ lawọn yoo tun ṣe nigba ti ibo gomina naa, nitori awọn ti ṣetan lati gba Eko lọwọ ijọba amunisin, to jẹ pe ẹgbẹ oṣelu kan lo n dari Eko lato bi ọdun mẹrinlelogun sẹyin.

 

O ni inu iṣọkan lawọn wa labẹ oun toun jẹ alaga wọn atawọn oloye ẹgbẹ yooku. Wọn wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko, lati jade dibo wọn pẹlu kaadi alalopẹ PVC 

No comments:

Post a Comment

Pages