Ẹ́gbẹ́ OPC New-Era ní Olódùmarè ló fi Tinubu ṣe ààrẹ orílèèdè yìí - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 4 March 2023

Ẹ́gbẹ́ OPC New-Era ní Olódùmarè ló fi Tinubu ṣe ààrẹ orílèèdè yìí



Aarẹ ẹgbẹ OPC, New-Era, Oloye Rasak Arogundade, tọpọ mọ si Saddam, ti sọ pe Olodumare lo yan Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bi aarẹ tuntun fun orileede yii lati fopin si idaamu to n de ba wa.

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa gbe jade lati fi ki Tinubu ku oriire fun ti ipo aarẹ ti wọn dibo yan an fun. O sọ pe gbogbo awọn lo ba a dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bo ṣe jawe olubori  bi aarẹ kẹrindinlogun lorileede yii.

Aarẹ OPC New Era, tun fi kun un pe atilẹyin Olodumare lo jẹ ko ni ipinnu lati jade, to si gba fọọmu, to si wa pẹlu ẹ titi to fi wọle, lẹyin gbogbo ipenija ti wọn ti foju ẹ ri lakooko pamari atigba ti ibo gbogbogboo waye.

O tun sọ pe, ‘’ Baba, latigba ti ẹ ti fi igboya sọrọ jade niluu Abẹokuta, pe ẹyin lo kan, inu waa dun pe Ọlọrun waa muṣẹ fun yin, pẹlu gbogbo awọn ọrọkọrọ tawọn kan sọ, eebu loriṣiriṣi, ẹ pada ṣe aṣeyọri’’

Bẹẹ lo tun sọ pe iduunu lo jẹ fawọn pe latigba ti ijọba tiwa-n-tiwa ti bẹrẹ lọdun 1999, awọn ti wa lọna tootọ, lati sọ pe wọn yan aarẹ  nipasẹ ibo yii ẹyin ni ẹni akọkọ to ja fun June 12, lati fopin si aṣẹ oloogun nigba naa lọhun.

O waa sọ pe o dawọn loju pe pẹlu bi Tinubu ṣe jawe olubori,orileede yii tun ti goke gba ju bo ṣe ri tẹlẹ lọ. Bẹẹ lo ni awọn tun nigbagbọ lati akoko naa lọ opin yoo bẹrẹ si ni de ba iṣoro to n koju wa lori aabo ẹmi ati dukia, ounjẹ ati atawọn nnkan mii-in, ti irọrun yoo si de ba wa lapapọ.

O ni gẹgẹ bi Tinubu tun ṣe sọ ni Ado-Ekiti,pe Yoruba ki i ṣe ẹru, bi ko ṣe eeyan pataki lawujọ, O waa lo akoko naa lati ri pe oludije aarẹ ọhun lo anfaani naa lati yanju aawọ to wa laarin ẹ ati awọn iran Yoruba yooku.


No comments:

Post a Comment

Pages