Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, to jẹ oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti gboriyin fun ajọ eleto idibo lori ọna ti wọn gba fi ṣeto ibo to waye nipa ṣiṣe amulo BVAS.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to kopa nibi ibo ti wọn di ọhun, eyi to ṣe tiẹ ni wọọdu kẹfa, Oju Agẹmọ, bẹẹ lo tun fi iduunu ẹ han lori bi ibo naa ṣe waye nirọwọ-rọsẹ. O sọ pe bi pẹlu bi iṣoro owo naira ti n koju awọn eeyan to, sibẹ wọn jade lati waa dibo fun ẹni ti ọkan wọn n fẹ.
Ṣẹgun Ṣowumi sọ pe ‘’ Pẹlu awọn nnkan ti mo ti foju mi ri, eto idibo naa lọ ni rọwọrọsẹ, mo si nigbagbọ pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, ayọ lo maa gbẹyin’’
“ Awọn eeyan ti mura lati lati dibo wọn fun ẹni ti wọn n fẹ, gbogbo wọn si n tu yẹyẹ jade titi lati waa ṣe ojuṣe wọn titi ti igba ti wọn da pe yoo pari, koda alaga wọn sọ pe bi igba naa ba to tawọn eeyan si wa lori ila, wọn gbọdọ fun wọn laaye lati dibo’’
No comments:
Post a Comment