Bi ibo aarẹ ati awọn aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin ṣe n waye lonii, Wolii Israel Ọladele Ogundipẹ, ti ijọ Genesis Global Church, ti gba gbogbo awọn ọmọ orileede yii nimọran lati jẹ ki ibo ọhun lọ ni alaafia, ki wọn ma ṣe gba rogbodiyan laaye.
Ninu atẹjade kan to fi sita, lo ti sọ pe ohun to le mu ki alaafia jọba, ki ibo si lọ nirọwọ-rọsẹ ni tawọn ọmọ orileede yii ba mọ iwọn ara wọn, nibi ti wọn yoo ti dibo, ki wọn si kọju mọ nnkan ti wọn waa ṣe.
Bẹẹ lo tun rọ wọn ki wọn ma ṣe faaye gba awọn ọrọ ti ko nitumọ tabi ede aiyede nibi ti wọn ba ti fẹẹ dibo. O waa sọ pe ireti wa pe gbogbo idojukọ to n waye lakooko yii fawọn ọmọ orileede yii ni yoo pada di ohun itan,
Ati pe akoko si n bọ ti a n bọ waa gbe igbe aye rere,. Amọ ṣa, eyi to sọ pe o ṣe pataki ni pe ki alaafia jọba nibi ibo tonii, ki a si maa ranti ọjọ iwaju awọn iran ti wọn ko tii daye ninu gbogbo nnkan ta a ba n ṣe.
Bẹẹ lo sọ pe ki wọn tun fi Ọlọrun si akọkọ ninu ibo naa, ẹni ti ẹri ọkan wọn ba ni ki wọn dibo fun un, ni ki wọn ṣe bẹẹ fun.
No comments:
Post a Comment