Ọtẹgbẹyẹ fi ọkan awọn ọba alade ti Dapọ Abiọdun gba ade lori wọn balẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 8 February 2023

Ọtẹgbẹyẹ fi ọkan awọn ọba alade ti Dapọ Abiọdun gba ade lori wọn balẹ Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti fi ọkan awọn ọba alade ti Gomna Dapọ Abiọdun, gbade lori wọn balẹ pe gbogbo wọn ni yoo pada sori aleefa awọn babanla wọn, toun ba ti wọle ninu ibo to n bọ ninu oṣu kẹta ọdun yii.

 

Bẹẹ lo sọ pe oun yoo fun wọn ni ọwọ ati iyi to ba yẹ fun wọn, lati le jẹ ki ogo wọn pada ninu iṣejọba oun, Ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita, lo ti sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ Gomina Abiọdun kọ lati da awọn ọba alade ọhun pada, pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe paṣẹ pe ko ṣe.

 

Ninu ọrọ ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ sọ ni afin ọba Magboro, Ọba Mọdiu Ademuyiwa, nijọba ibilẹ Ọbọfẹmi Owode, lakooko to gbe ipolongo ẹ lọ sibẹ lo ti sọ pe oun yoo rii pe oun pa aṣẹ ile ẹjọ mọ, bi oun ba le gori aleefa ninu ibo ọhun.

 

 A o ranti pe awọn ọba marundinlọgọrin, nijọba Amosun yan, ko to di pe o gbe ijọba silẹ lọdun 2019, to si jẹ pe bi Gomina Dapọ Abiọdun ṣr gba akoso lo le awọn ọba alade naa danu, pẹlu bi ile ẹjọ, ṣe paṣẹ pe ko gba wọn pada sibẹ pabo ni gbogbo rẹ ja si.

 

Ọtẹgbẹyẹ tun ṣalaye pe wọn ko ti ni ijọba ti ko bọwọ faṣẹ ile ẹjọ bi ti Dapọ Abiọdun yii, ti ko si tun ni ibọwọ fawọn ọba alaye. O waa beere pe bawo ni wọn ṣe le yan awọn pẹlu ibofin mu, ki o wa yọ wọn laibikita.

 

 

O ni koda ẹẹmeji ọtọọtọ lawọn ọba yii gba idalare nile ẹjọ ṣugbọn ti Dapọ Abiọdun ko ri tawọn ọba naa ro rara,  o ni kaka ko ṣe nnkan to lẹtọọ, ṣe lo pinnu lati maa ja irawọ awọn ọba.

 

Ọtẹgbẹyẹ tun sọrọ siwaju ‘’ Mo mu da gbogbo ẹyin eeyan gidi ipinlẹ Ogun loju, paapaa ẹyin ọba alade, pe ijọba ADC, labẹ mi yoo bọwọ fun aṣẹ ile ẹjọ, ti mo si maa da gbogbo awọn ọba ti ọrọ naa kan pada si ori aleefa nipaṣẹ awọn idajọ to ti waye’’

 

Nigba to n sọrọ, Olu tilu Magboro, dupẹ lọwọ Ọytẹgbẹyẹ lori bo ṣe ya waa ki oun ni afin ẹ, o waa gbadura fun un pẹlu ileri pe awọn yoo ṣe atilẹyin to lagbara,ko le ba jawe olubori ninu ibo to n bọ ọhun.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages