E fi kaadi idibo PVC yin gba ijoba APC danu nipinle Ogun -Oludije Gomina Action Alliance - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 8 February 2023

E fi kaadi idibo PVC yin gba ijoba APC danu nipinle Ogun -Oludije Gomina Action Alliance



Oludije Gomina labe egbe oselu Action Alliance, nipinle Ogun Dokita Samuel Adeyemi, ti muu da gbogbo awon osise-feyinti loju pe gbogbo gbese tijoba je won loun yoo rii pe o di sisan toun ko nii je won ni gbese ti won ba le dibo yan oun wole ninu ibo to n bo laipe yii.

Okunrin naa soro yii nibi ayeye ibere ipolongo e, eyi to waye lojo Aje, Monde, ose yii. O so pe edun okan lo n je foun lori bi won ko se je kawon osise-feyinti naa maa gbowo won lakooko, ti won si tun je won lowo.

Oludije Gomina naa tun fikun oro e pe bo tile je pe oun ti se ipade pelu won,toun si ti seleri pe laaarin osu mejila akoko toun ba gbajoba, ti won ba dibo foun wole loun yoo San gbogbo ajeele owo won pata.

O so pe ko seni ti Inu e yoo dun lori ipo tawon osise-feyinti naa wa, nitori bi won ko se mayederun fun won. O ni opo won lo ye ki won maa fi ojo ogbo won sinmi, ki won si maa je nnkan gidi amo tijoba ko je nipase airi awon eto won yii gba.

Adeyemi so pe o se ni laaanu pe opo awon osise-feyinti yii ni won ti je ki ironu so di alaisan,ti won ko si rowo toju ara won. O waa mu da won loju pe gbogbo eyi ni yoo dopin laipe.

O so pe oun naa mo pe ko rorun lati san owo naa laarin osu mejila toun so sugbon oun yoo rin irinajo lo si oke okun lati bawon omo ipinle Ogun to nibe soro lati kopa to joju.

O ni oun mo pe o kere ju awon yoo ri bii milionu aadota si ogota dola,lati fi san owo naa.

A o ranti pe laaarin osu meta si ara won nijoba to wa lode yii san milionu lona eedegbeta naira fawon osise-feyinti ti won fi n yanju awon owo ti won ti je won tele.

Bakan naa lo tun seleri fun gbogbo omo ipinle Ogun pe won ko nii kabamo pe won dibo foun, ti won ba le fi ibo won gbe oun wole,o ni egbe oselu Action Alliance nikan lo le yanju isoro to n koju won.

Bee lo tun ro awon araalu lati fi kaadi idibo alalope iyen PVC won gba APC danu lojo kokanla osu keta odun yii.







No comments:

Post a Comment

Pages