Ko si nnkan to le mu ki wọn sun ibo to n bọ siwaju- Salvador - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 17 February 2023

Ko si nnkan to le mu ki wọn sun ibo to n bọ siwaju- Salvador



Ọnarebu Moshood Adegoke Salvador, oludije fun ipo aṣofin agba fun ẹkun Lagos West  niluu Abuja labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, ti sọ pe ko si nnkan ti wọn fi le sun ibo ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ yii, iyẹn ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keji.

O sọrọ naa lakooko to n ba oniroyin wa sọrọ lori foonu lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, o sọ pe ijọba apapọ ti wa ni imurasilẹ lati jẹ ki ibo ọhun waye lọjọ ti  wọn da naa bẹẹ lawọn ajọ eleto idibo naa ti n gbaradi.

Oludije aṣofin  ọhun tun sọ pe ''Ki lo de ti wọn sa fun ojiji ara wọn, bi ẹ ba sun siwaju, ojiji yin naa ma a sun siwaju, bẹẹ naa ni bi ẹ ba sun mọ ẹyin, yoo tun ṣe bẹẹ gẹlẹ, ki lo wa de ti ẹ ko duro soju kan''.

''Ko si nnkankan to wa ninu ki wọn fi ọjọ kun ọjọ idibo, ko si idi ti wọn fẹẹ fi kun, ijọba si ti duro pe  ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu yii, lawọn yoo ṣeto ibo wọn, o  si ti di ṣiṣe, awa naa si ti ni imurasilẹ''

Bẹẹ lo tun sọ pe ọkan oun balẹ digbi lori ibo ti yoo waye naa nitori bawọn eeyan to fẹẹ lọ ṣoju fun ṣe n fi atilẹyin wọn han. O ni bo tilẹ jẹ pe ipolongo ile sile loun ṣe, lati fi bawọn sọrọ.

Salvador tun ṣalaye siwaju pe,'' Gbogbo nnkan lọ letoleto, o ni bi mo ṣe maa n ṣe nnkan temi,o gbọdọ yatọ si tawọn yooku, ile si ile ni mo gbe ipolongo mi le lori''.

''Mi o ki i ṣe alejo wọn, koda, awọn musulumi kan tiẹ ranṣẹ si mi, mo ni lati ran eeyan lọ ni, wọn sọ pe nigba tawọn ri posita mi, awọn ko si mọ ẹni tawọn le ri''.

''Wọn sọ pe nitori ọdọọdun lawọn maa n wa gba nnkan ọdun lọdọ mi nibi. o si to asiko tawọn ni lati fi ifẹ han. Ifẹ tawọn si le fi san fun mi ni pe kawọn dibo fun mi ninu ibo naa''

Bẹẹ lo sọ pe loootọ ni awọn kan dunkoko mọ awọn oloṣelu kan ti wọn kọlu wọn amọ wọn ko le ṣe bẹẹ si oun, nitori ara wọn loun

No comments:

Post a Comment

Pages