Ibo Gomina 2023:Biyi Otegbeye di eru jeje si Dapo Abiodun lorun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 15 February 2023

Ibo Gomina 2023:Biyi Otegbeye di eru jeje si Dapo Abiodun lorun



Bi won ba ni ta ni ko fi okan Gomina Dapo Abiodun ati egbe oselu APC tipinle Ogun bale lakooko yii, Agbejoro Biyi Otegbeye toun naa dije fun ipo yii lane egbe oselu ADC ni.

Titi di akoko yii ni won fi n so ara won lowo lese, to si je bi oludije naa se n tu asiiri won,lawon  naa dogbon fesi pada.

Eyi to tun n mu iberubojo bawpn gege bi a se gbo ni bawon araalu to fi mo  awon oba alaye se n fojoojumo fatileyin won si Biyi Otegbeye.

Sebi ero ti won so pe won n ro  ni pe okunrin naa ko nii gba idalare lori ejo kotemilorun to pe lori idajo ile-ejo giga kan niluu Abeokuta, nibi ti Adajo ti koko pase pe ki ajo eleto idibo yo oruko Biyi Otegbeye Kuro gege bi oludije gomina.

Eyi to ko irewesi ati ifaseyin ba ADC pelu aheso ti won lawon alatako oselu n so kaakiri lati fi le tubo ko irewesi ba won.

Sugbon biri ni oro yii, nigbati Ile ejo kotemilorun niluu Ibadan da Otegbeye lare, ni ilu ba yi ti orin naa senji, ti won ni ibanuje okan de ba awon alatako oselu yii.

Logan ni Biyi Otegbeye sefilole ipolongo e ni Ake niluu Abeokuta, nibi ti Seneto Ibikunle Amosun tun ti fa owo e soke pe eyii ni ayanfe oun, eni ti Inu oun dun si gidigidi, kawon eeyan maa gbo tie.

Latigba naa lo si ti bere ipolongo e kaakiri ipomle Ogun, ti won si n gba ni towo tese, amo ogulutu ti okunrin naa ba so si ijoba to wa lode yii, ki i bawon nibi to dara, ti won yoo si maa wi awaawi.

Awon nnkan to ye ki won ti se to ye ki won gba iyi nibe latojo pipe ti won lo se afi igba ti Otegbeye to hu jade ni won to n sare kaakiri.
Ekunrere ati esi won n bo ninu apa keji.

No comments:

Post a Comment

Pages