Segun Sowumi binu tan:O ni omo asegita oun yato si omo olowo to n gbowo lowo awon oludije - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 15 February 2023

Segun Sowumi binu tan:O ni omo asegita oun yato si omo olowo to n gbowo lowo awon oludijeOtunba Segun Sowumi, oludije fun ipo gomina labe egbe oselu PDP nipinle Ogun, ti so pe loooto lawon kan le ma pe ara won ni omo baba olowo, sugbon oun tawon yo nitori omo asegita oun yato si omo olowo to tun gbowo kaakiri lowo awon oludije e.

Okunrin naa soro yii lakooko ti won n se idanilekoo tawon ti yoo soju won lawon woodu ati eka fun ti ibo to n bo lona naa, eyi to waye niluu Abeokuta.

O so pe ki won ma se je ki enikeni tan won je, igbejo Ile ejo to ga ju lo ni ireti si wa pe yoo gbe idajo e kale laipe, pelu igbagbo pe oun yoo jawe olubori.

O ni gbogbo eyi ti Ladi Adebutu si n se yen ki won fi sile titi ti idajo naa yoo fi waye, eyi to so pe yoo bori gbogbo eyi to ti wa nile.

Bee lo so pe oun gbo pe awon kan dunkoko mo awon omo eyin oun, o ni kawon eeyan sora, ki won ma te iru oka mole, ki won maa to oun, nitori ibinu oun ko dara.

Sowumi tun so pe ki i binu, omo ale lo n fa, oun setan lati gbe igbese ofin le enikeni to ba to awon omo eyin oun.

Bee lo ro awon asoju naa lati pada sile ki won lo maa size lori bi egbe oselu PDP yoo se jawe olubori ninu ibo ti yoo koko waye, iyen ibo aare, lojo keeedogbon, osu keji, odun yii.

O je ki won mo pe ibo ti yoo waye naa no yoo so bi ibo yooku yoo se ri, o ni eleyii yato si omo eni ki i se idi bebere, ki a gbe fun omo elomii-in.

Sowumi wa so pe oro to wa nile lakooko yii ninu egbe naa ki i se ija rara, bi ko se pe ki won jo pawopo ki PDP Wole.

Bee lo ni ki won sora fun adile ibo, nitori  ajo INEC, ti so pe ibikibi ti iru nnkan bee ba ti waye won yoo wogile ibo Ibe ni.

O waa seleri pe eto ti wa nile lati owo ara oun toun yoo se fun eka tabi woodu ti PDP ba ti ni ibo to poju..

No comments:

Post a Comment

Pages