Dàpọ̀ Abíọdún ti bá ǹnkan jẹ́ jìnnà fáwọn Yewa- Àwórì-Ọ̀tẹ̀gbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 18 February 2023

Dàpọ̀ Abíọdún ti bá ǹnkan jẹ́ jìnnà fáwọn Yewa- Àwórì-Ọ̀tẹ̀gbeyeLọsẹ to kọja, ni Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije fun ipo gpomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC,  tun ti fẹsun kan Gomina Dapọ Abiọdun ati ijọba ẹ lori bo ṣe ba nnkan jẹ fawọn Yewa-Awori.

O sọrọ yii lakooko to gbe ipolongo ẹ lọ si Ipokia lọsẹ to kọja, o sọ pe ọpọ iṣẹ akanṣe to yẹ ko jẹ nnkan iwuri fun wọn, lo ti pati ti ko si ya si mọ titi di onii. Lara ẹ ni ileewe poli ti wọn kọ si Ipokia.

Oludije naa sọ pe ijọba to kogba sile ki Dapọ Abiọdun to o gba, iyẹn Sẹnetọ Ibikunle Amosun, lo ṣe idasilẹ ileewe ọhun ṣugbọn ti wọn ko jẹ ko di mimulo latigba naa titi di akoko yii.

O sọ pe ogo nla nileewe ọhun ko ba jẹ fun ilẹ Yewa-Awori, to ba jẹ pe wọn ti n lo ileewe naa. O ni ẹdun ọkan lo jẹ pe ṣe ni wọn ko jẹ ki iṣẹ bẹrẹ nibẹ to si tun  mu ọwọ idagbasoke fa sẹyin nibẹ.

Ọtẹgbẹyẹ tun ṣalaye pe gbogbo ọna ni ijọba ADC yoo gba ti wọn ba le dibo foun ko wọle, lati da gbogbo nnkan wọnyii pada, awọn nigbagbọ pe awọn le ṣe lati le jẹ ki iṣẹ bẹrẹ nileewe ọhun.

O sọ pe ọrọ aje ko ba tun ti gbooro soke ka ni Gomina Dapọ Abiọdun ko da ọwọ ileewe poli naa duro. O ni pẹlu ipo etọ ẹkọ ni Ogun West, ileewe poli yii ti to lati pese iṣẹ fawọn ọpọ eeyan nipinlẹ Ogun.

 


No comments:

Post a Comment

Pages