E fi ibo yin gbe AbdulRazak Abdulrahaman wole gege bi Gomina Kwara leekeji-Onarebu Mariam Bola Yusuf - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 19 February 2023

E fi ibo yin gbe AbdulRazak Abdulrahaman wole gege bi Gomina Kwara leekeji-Onarebu Mariam Bola YusufỌnarebu Mariam Bọla Yusuf Yusuf, oludasilẹ ileeṣẹ God of Fuilment Travel and Tour, iyẹn awọn to n ri si bi eeyan ṣe le rin irinajo kaakiri, ti rọ awọn eeyan ipinlẹ Kwara, lati ṣatilẹyin fun Gomina AbdulRahman Abdulrasaq, fun ti ibo gomina ẹlẹẹkeji, ti yoo waye ninu oṣu kẹta ọdun yii.

 

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin oloyinbo kan, 1steleven9jatv, sọrọ, o sọ pe pẹlu awọn aṣeyọri ti Gomina ti ṣe ni saa akọkọ to n lo lọọ yii, o kun oju oṣuwọn lati ṣe ẹlẹẹkeji nitori awọn iṣẹ ẹ si n tọ ọ lẹyin.

 

Ọnarebu naa tun fikun pe lakooko ta a wa yii Gomina Abdulrasaq lawọn ara ipinlẹ Kwara n fẹ lati waa tẹsiwaju ninu iṣẹ to n ṣe, ki awọn idagbasoke tubọ tẹsiwaju ni ipinlẹ naa.

 

O sọ pe’’ Bi a ba ni ki a woo, gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Kwara lo ti foju ri awọn iṣẹ rere ti Gomina wa ṣe, ọpọ wa la si le jẹri sii pe o mu ayipada rere ba ipinlẹ wa’’

 

O waa rọ awọn eeyan yii lati lo kaadi idibo wọn ki wọn fi dibo fun Gomina aṣaaju rere yii tinu ẹgbẹ oṣelu APC.

 

No comments:

Post a Comment

Pages