Eyi ni bi ibo ṣe waye kaakiri ipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 25 February 2023

Eyi ni bi ibo ṣe waye kaakiri ipinlẹ OgunKi i ṣe tuntun mọ pe ibo aarẹ ati aṣofin waye kaakiri orileede yii, nibi tawọn araalu ti tu jade lati dibo fawọn to wu wọn. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri nipinlẹ Ogun,  tawọn eeyan jade bakan naa.

Lati nnkan bi aago meje aarọ lawọn araalu ti n jade pẹlu kaadi ibo PVC wọn lọ si ibudo ti wọn la kalẹ fun wọn. Awọn oṣiṣẹ eleto idibo gan an ko si fiṣẹ wọn falẹ rara. Bo tilẹ jẹ pe ọpọ idojukọ lawọn eeyan naa koja ni awọn agbegbe kan, to fi di pe wọn ko le gbe orukọ wọn jade.

Ohun to si faa ni pe ẹrọ BVAS, ko gbe orukọ wọn jade, eyi to si jẹ ki wọn paara bi ẹẹmeji si ẹmẹẹta, to si jẹ pabo ni gbogbo rẹ ja si,lara awọn to foju winna iru nnkan bẹẹ ni Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba, to jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun. Ẹmeeji ọtọọtọ lo para ibudo to yẹ ko ti dibo ni  

 

 Tinubu jawe olubori ni wọọdu Ọbasanjọ, ṣe  ni Obi lulẹ ni wọọdu kẹẹẹdogun, ẹka kẹrinla, Ọmọlolu House,  Ibara Housing, niluu Abeokuta, nigba ti baba naa ri i pe ko ṣe e ṣe loun naa ba gba kamu. To si fi ọkan akin gbe.

 

Ṣugbọn ni wọọdu kẹta, ni Ita-Ọsanyin,Ipẹru, nibi ti Gomina Dapọ Abiọdun, lo ti ba awọn oniroyin sọrọ pe pẹlu gbogbo nnakn toun ti ri, ibo ọjọ naa lọ nirọwọ rọsẹ,o ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ idojukọ lo ti kọkọ waye ni aarọ ọjọ naa nitori bwaọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu ti sọ foun pe wọn ko rti kaadi lawon ibi ti ibo ọhun ti waye, ṣugbọn oun nigbagbọ pe igbesẹ ti n lọ lati yanju gbogbo ẹ.

 

No comments:

Post a Comment

Pages