Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti rọ ajọ eleto idibo lorileede yii, iyẹn INEC, lati tete wa nnkan ṣe si ẹrọ to n ṣayẹwo orukọ awọn oludibo jade iyẹn BVAS, ko to digba wọn yoo dibo gomina, eyi ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun yii.
O sọrọ yii lakooko to n dibo ẹ ni wọọdu Kin in ni, ẹka kin in ni, Ilaro, nipinlẹ Ogun. O sọ pe bo tilẹ jẹ pe igbesẹ BVAS, naa dara pupọ, amọ wọn gbọdọ ṣiṣẹ lati wa ọna abayọ si iṣoro ti wọn koju lakooko ibo aarẹ to waye ọhun.
O fikun ọrọ ẹ pe ni ọpọ awọn ibi ti ibo ọhun ti waye ni awọn ẹrọ ti wọn lo ko le ya fọto awọn oludibo bẹẹ lo si jẹ pe awọn kan ko ri orukọ wọn. O ṣalaye pe inu oun dun pe awọn eeyan jade daadaa lati waa dibo.
Oludije Gomina naa tun sọ pe, ‘’ O gba mi niṣẹju mẹrin si mẹfa ko to di pe mo pari awọn igbesẹ to yẹ, inu mi si dun pe o yọri si rere.. Awọn oṣiṣẹ eleto idibo naa kọju mọ iṣẹ wọn, ti wọn si n da awọn eeyan lohun.
Mo tun ṣe akiyesi pe awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu naa wa pa. ti gbogbo ẹ so lọ bo ṣe yẹ ko lọ. Ṣugbọn awṣn kudiẹ- kudiẹ kan wa nitori mo gbọ pe awọn ti orukọ wọn bẹrẹ lati A si J, wọn ko le dibo nitori akude ti ẹrọ BVAS mu bawọn’’
“ BVAS yii ko gba awọn orukọ ni tẹletẹle, a si gbọ pe eọn ti fọrọ naa to awọn to wa nidi ẹ leti, ti wọn yoo si ṣe atunṣe lee lori. Pẹlu eyi wọn ko jẹ ki irẹwẹsi ba wọn, ṣe ni wọn tun duro, a si ni ireti pe atunṣe yoo waye ko to di akoko ibo gomina to n bọ’’.
No comments:
Post a Comment