Eyi lawọn aṣeyọri wa fun ọdun kan- Ọga agba kọsitọọmu nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 19 January 2023

Eyi lawọn aṣeyọri wa fun ọdun kan- Ọga agba kọsitọọmu nipinlẹ Ogun




Ọga agba fajọ ẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Bamidele Makinde, ti sọ pe gbogbo awọn owo ti wọn pa wọle laarin ọdun 2022, to kọja yii, fẹẹ to miliọnu mẹtadinlọgọrin, ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹwa Naira, N97,887,777.50, eyi to jẹ ida ọọdunrun ju ti ọdun 2021.

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin fọrọjomitoro ọrọ lori awọn aṣeyọri wọn fọdun to kọja, O sọ pe idunuu lo jẹ ileeṣẹ naa powo wọle ju ti atẹhinwa lọ.

O sọ lọdun 2021, owo ti wọn pa wọlẹ nigba naa jẹ miliọnu mẹtadinlogoji ati ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta le diẹ Naira. O ni akọsilẹ tawọn ni fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹrun marundinlaadọta ati ẹẹdẹgbẹta le mẹtalelaadọrin baagi irẹsi lawọn ri gba lọdọ awọn fayawọ, eyi to jẹ pe tirela mẹrindinlọgọrin.Awọn yooku tun ni tanka epo pẹtiroolu mẹrinla, tanka diisu ẹyọ kan,Igbo apo mẹtalelogoji.



Awọn yooku tun ni ogun tiramadọlu ẹgbẹrun meji ati igba le ni aadọta, aloku ọkada ọgbọn, aloku aṣọ, baagi. Taya, ẹrọ amunnkan tutu, baagi simenti Dangote ti wọn ko irẹsi si atawọn nnan mii-in.

Makinde tun fi kun ọrọ ẹ pe awọn afurasi fayawọ mẹẹẹdogun lọwọ awọn tẹ kaakiri ipinlẹ Ogun, nigba ti wọn gba beeli ninu wọn tawọn mii-in yoo si foju bale-ẹjọ laipẹ.

Bẹẹ lo sọ pe awọn rii pe ajọṣepọ to danmọran wa laarin araalu nipa ọrọ okoowo, pẹlu idaniloju pe yoo tubọ tẹsiwaju, tawọn yoo si ri atilẹyin wọn gba. O sọ pe awọn rii pe wọn da ẹgbẹ agbabọọlu silẹ to n n je Customs FC, eyi to fun ọpọ awọn ọdọ to wa lagbegbe naa lanfaani lati darapọ mọ wọn.



 O ṣalaye pe ajọṣepọ wọn pẹlu awọn ọba alaye, awọn olori ilu, olori ẹlẹsin,awọn ọdọ atawọn alaabo ilu yooku tubọ peleke si to si tubọ ran wọn lọwọ fawọn aṣeyọri ti wọn ṣe.

Bo ṣe sọ nipa awọn iṣẹ wọn lo tun mẹnuba bi wọn ṣe padannu ọkan lara wọn, to ku sinu ijamba mọto lakooko to wa lẹnu iṣẹ ẹ ni ọna Ebute axis, ni Yewa North, nigba ti dẹrẹba kan ṣadeede lọ gba wọn, to si ku loju ẹsẹ..

O waa pari ọrọ ẹ pe gbogbo akitiyan wọnyii mu ki idagbasoke ba ọrọ aje ati eto aabo nipinlẹ Ogun, pẹlu ileri pe awọn yoo tubọ tẹsiwaju ninu iṣẹ wọn.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages