Ẹ ye dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa mọ nigboro Eko- Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 18 January 2023

Ẹ ye dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu wa mọ nigboro Eko- Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour



Alaga fidihẹ fẹgbẹ oṣelu Labour ti wọn ṣẹṣẹ yan nipinlẹ Eko, ti kilọ fun gbogbo awọn to maa n dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn nipinlẹ naa pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, nitori lati akoko yii lọ awọn ko nii gba iru ẹ mọ.

Obinrin naa sọrọ yii ni ọfiisi ẹgbẹ wọn to wa ni Allen, niluu Eko lakoko ti wọn ṣe ibura fawọn oloye fidihẹ tuntun ẹgbẹ wa, eyi to jẹ alaga wọn. O sọ pe oun rọ awọn ti maa n yẹyẹ tabi kan awọn ọmọ ẹgbẹ naa nigboro lati jawọ nitori awọn ṣetan lati fọwọ ofin mu ẹnikẹni to ba tun da aṣa iru ẹ wo.

O sọ pe ki i ṣe nnkan to dara nibi ti oju la de kawọn kan maa tori oṣelu maa dunkoko mọ awọn kan, o ni ko yẹ ko ribẹ ati pe opin gbọdọ deba, nitori ibikibi tawọn ba ti gbọ pe wọn tun ṣe bẹẹ ni Eko, pfin lawọn yoo fi yanju ẹ.

Bakan naa lobinrin naa tun sọ pe pẹlu ibura ti wọn ṣe fawọn fidihẹ oloye tuntun ẹgbẹ ọhun, ko si nnkan to n jẹ igun mọ ati pe awọn ti parapọ ẹyọ kan. O sọ pe nnkan to wa niwaju awọn bayii ni bi ẹgbẹ ọhun yoo ṣe lọ soke ati jawe olubori ninu ibo to n bọ lọna naa.

Dayọ Ekong, tun sọ pe iduro ko si bẹẹ ni ibẹrẹ ko si mọ bayii, nitori iwọnba perete to ku ki ibo yoo fi waye, awọn ṣetan lati polongo ẹgbẹ naa kaakiri ati pe inu oun tiẹ dun pe ojoojumọ lawọn araalu n gba ti ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko.

O sọ pẹlu idaniloju pe Peter Obi to jẹ oludije aarẹ ẹgbẹ naa ni yoo jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ, nigba ti Ọgbẹni Gbadebọ Rhodes-Vivour, to jẹ oludije gomina fẹgbẹ naa yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ naa.

Ninu ọrọ Agbẹjọro Akingbade Oyele, to oludamọran nipa ofin fẹgbẹ naa lapapọ sọ lẹyin to ṣebura fawọn mẹẹẹdọgbọn oloye tuntun fidihẹ ọhun tan lo ti sọ pe awọn eeyan naa ni alaga ẹgbẹ wọn lapapọ fọwọsi ati pe ẹnikẹni to ba pe ara ẹ ni oloye ẹgbẹ lẹyin awọn ti wọn yan an yi, ki wọn fi ọwọ ofin mu.


No comments:

Post a Comment

Pages