Nitori Yayi, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC darapọ mọ APC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 18 January 2023

Nitori Yayi, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC darapọ mọ APC



 

Biri ni ọrọ oṣelu yi ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC ni Yewa South, Yewa North ati ni Ado Odo Ota, nigba tawọn alẹnu lọrọ ninu ẹgbẹ ọhun lọ darapọ mọ APC, lati ṣiṣẹ fun Sẹnatọ Solomon Adeola, tọpọ mọ Yayi, fun ipo aṣofin agba fun ẹkun Ogun West, ninu ibo to n bọ lọna yii.

 

Tawọn eeyan ọhun ti Onimọ-Ẹrọ Tommy Akintomide tọpọ mọ si Tommy Toaks ati Ọnarebu Temitọpẹ Akinoṣo, toun jẹ alaga fẹgbẹ oṣelu, ADC ni Yewa South, ṣaaju wọn wa sibi ayẹyẹ to waye ni papa iṣere Asade Agunloye Ultra Modern Pavillion, niluu Ilaro, lawọn ni wọn ti sọ pe Yayi lawọn n ba lọ bayii.

 



Nigba ti wọn sọrọ lọjọ naa, Sẹnetọ Adeọla sọ pe inu oun dun bi lawọn ọgọrun-un ti wọn jẹ aṣaaju ninu ẹgbẹ ADC, ṣe fi ẹgbẹ wọn silẹ darapọ mọ APC, paapaa julọ Onimọ-Ẹrọ, Akintomide atawọn eeyan ẹ.

 

O ni ọkunrin naa wa lara awọn agba ilẹ Yewa, to ki oun kaabọ pada wa sile ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin niluu Ilaro. O sọ pe idunnu nla lo jẹ pẹ Baba oun, Baba Akintomide, wa darapa mọ awọn agba Yewa yooku bi Oloye Iyabọ Apampa, Ọnarebu Muftau Ajibọla, Oloye Olu Agẹmọ,Ọnarebu Bisiriyu Popoọla atawọn yooku ti wọn jọ bẹrẹ papọ, ni nnkan bii ọdun meloo kan sẹyin. Bẹẹ lo nii nu oun tun tun dun lati gba awọn ọmọ ẹyin baba naa pada si APC.

 



Bẹẹ ni Yayi tun fikun ninu ọrọ ẹ pe gbogbo ẹtọ lawọn ti wọn ṣẹṣẹ darapọ naa ni lati apapọ de ibilẹ ninu ẹgbẹ naa fgun ifdibo to n bọ ati pe ọmọ ale Yoruba nikan lo lre sọ pe ki awọn to wa nilẹ Hausa tun wa sakoso wa lorileede yii.

 

O waa bẹbẹ atilẹyin fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati dibo fun un gẹgẹ bi aarẹ orileede yii, bakan naa lo ni ki wọn ṣe bẹẹ fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun, fun ipo gomina nipinlẹ Ogun, bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo tubọ maa sin awọn eeyan ẹ ti wọn ba fibo gbe oun wọle fun ipo sẹnetọ.

 

 

Ninu ọrọ Akintọmide ati Ọnarebu Akinoṣo, nibi ayẹyẹ igbaniwọle wọn, ni wọn ti sọ pe bawọn ṣe fẹẹ maa tẹle Yayi ninu ẹgbẹ APC, ki i ṣe abamọ rara, bi ko ṣe fun ifẹ inu awọn ọmọ ilẹ Yewa.

 

Pẹlu afikun pe awọn bii ọgọrun-un yooku ti wọn jọ darapọ yii ni wọn jẹ ojulowo kaakiri awọn wọọdu, ni wọn si sọ pe awọn yoo farahan nibi ipolongo ti wọn fẹẹ ṣe niluu Ilaro laipẹ.

 

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ ADC, ti wọn tun darapọ mọ APC ni, Ọmọọba Jimoh Akinlade,Ọnarebu Yinka Falẹyẹ, Sultan Akorede, A. Amore, Sẹrifat Idowu,atawọn yooku.

 


No comments:

Post a Comment

Pages