Ibo 2023: E je ki ileri Olorun ko wa si imuse- Wolii Israel Oladele Ogundipe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 19 January 2023

Ibo 2023: E je ki ileri Olorun ko wa si imuse- Wolii Israel Oladele OgundipeBo tile je pe o ku die ki ibo gbogbogboo ti odun 2023, waye, tawon araalu si ti wa ni imurasile,Wolii Isreal Oladele Ogundipe tijo  Genesis Global, ti  gba si Olorun lati je ki ileri e se fun ibo naa.

 Ojise Olorun naa so pe nigba ti a ba gba lati mu ileri Olorun se ni orileede yii yoo tubo dara ju ti bayii lo.

Okunrin naa soro yii ninu ise iranse to se laipe yii nibe lo ti waasu pe orileede yii je eyi ta a bukun fun pelu opo awon alumoni. Sugbon o so pe o se ni laanu pe awon adari to n dari wa n se bo se wu won.

Ogundipe so pe "Mo nigbagbo pe ti ileri Olorun ba bere si nii wa si imuse ninu ibo to n bo yii, Naijiria yoo bere si nii je eso rere lori ile".

Bee lo tun gba gbogbo awon omo orileede yii lamoran lati rii pe won dibo fawon oludije to kun oju osuwon, ki won ma se tori owo ta ogo ojo iwaju won nu gege bi Esau ati Jakobu ninu bibeli.

Wolii Isreal Oladele Ogundipe, je oniwaasu to n soro nipa imole ati ife,to gbaju mo ironupiwada ati igbe aye rere fawon eeyan.

No comments:

Post a Comment

Pages