Ẹsẹ o gbero ni gbọngan Edwin, lopin ọsẹ to kọja yii nigba tawọn gbajumọ eeyan lawujọ pejọ lati ṣayẹyẹ ikẹyin fun Iyaafin Felicia Abẹbi Adesọla Oriọla, tawọn eeyan tun mọ si Iya Ìṣán, ẹni to jẹ mama Olujimi Oriọla, tọpọ mọ si Oris, manija olorin nigba kan fun agba onifuji nni Alaaji Abass Obesere.
Ayẹyẹ ọhun ti wọn fi ọjọ meji ṣe lawọn ẹbi mama ọhun atawọn oloolufẹ ọmọ ẹ, Oris, ṣe ti wọn fi dagbere fun iya ọhun pe o digboṣe. Lẹyin to ti lọ ọdun marundinlaadọrun lori eepẹ.
Lọjọbo, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ti kọkọ ṣe isin aisun onigbagbọ fun Iya Ìṣán, nile ẹ to wa ni Abúlé-Ọlọ́nì, to wa niluu Abẹokuta. Nigba to si di ọjọ keji, ni wọn ṣe isin ikẹyin fun un ni ṣọọṣi St Micheal Angilcan, to wa ni Oke-Egunya, Agọọba, inu ọgba naa ti ile itẹ- oku wn wa naa ni wọn ti fi eeru fun eeru, eepẹ fun eepẹ.
Ko to wa do pe agba olorin fuji nni, Ṣina Akanni, tọpẹ mọ si Ọgọ lorin wa. Fere da awọn eeyan lara ya. Bakan naa ni Yọmi Matẹ, ti wọn tun pe ni Ifankalleluya, Makinde Fasunle, iyẹn Sẹnetọ awọn sọrọsọrọ ati Alado naa da awọn eeyan lara ya lọjọ naa.
No comments:
Post a Comment