Ope oo; Lojo Sannde yii ni Yayi yoo si afin Ishaga Orile tuntun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 15 December 2022

Ope oo; Lojo Sannde yii ni Yayi yoo si afin Ishaga Orile tuntun.
Gbogbo ona ni yoo ya si afin tuntun Ishaga Orile, lojo Aiku, Sannde, ojo kejidinlogun, osu yii, nigba ti Seneto Solomon Adeola Yayi, oludije fun ipo asofin agba niluu Abuja, fun ekun Ogun West, ba n si afin Onishaga tiluu Ishaga naa. 

Gege bi atejade ti Oloye Kayode Odunaro, to je oludamoran pataki fun eto iroyin asofin naa fi sita, lo ti so pe gbogbo tomode ati agba lokunrin ati lobinrin ni won ti wa ni igbaradi fun afin igbalode tuntun naa. 

Ninu oro Dokita Omooba Tunde Tella, nibi atejade yii lo ti salaye pe afin yii tawon eeyan agbegbe ilu naa ti bere tipe ni Seneto Adeola waa ko pari fun won. 


Okunrin naa so pe Yayi gba akoso sise afin yii nigba ti ko si agbara mo lodo awon araalu naa mo lati gbe debi ti won fe lokan won ti yoo fi dabi igbalode ti yoo si se dun un wo loju. 


Loju ese lo so pe oludije seneto labe egbe oselu APC, ti ni ki won bere ise, ti won si pari e. 

Koda Omooba Tella, to je akobi oba to  je ni Ishaga Orile, iyen Oba Joseph Tella, tun fikun oro e pe lara awon nnkan ti Yayi, to je Araba ilu naa tun se to fi mu idagbasoke ba ilu won yii ni pipese ero amunawa ti won pe ni tiransifoma ati ilera ofe fawon araalu

Bakan naa ni Odunaro tun so ninu atejade yii pe won tun fee fi ayeye sisi afin naa se ayayo Ishaga ati ojoobi Oba Tella, nibi ti gbogbo awon omo ilu naa ti won wa jakejado yoo ti wale, wa bawon se odun ibeta naa. 
No comments:

Post a Comment

Pages