Ko saaye fawon fayawo lati ko eru ofin wole lakooko odun- Oga Kositoomu. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 7 December 2022

Ko saaye fawon fayawo lati ko eru ofin wole lakooko odun- Oga Kositoomu.




Oga awon kositoomu nipinle Ogun, Bamidele Makinde, ti kilo fawon fayawo lati yera fun kiko awon eru ofin wole niwonba ki odun yii pari nitori awon ti setan lati gbena woju awon towo ba te. 

Okunrin naa soro yii nibi ipade oniroyin ti won se ni ofiisi won to wa ni Idi iroko, lakooko to n so nipa ise irinju won laaarin osu mesan an, to gbakoso.

O so pe awon ti wa nigbaradi fun ise odun ati pe onifayawo towo ba te yoo je iyan e nisu. 
 



Oga agba naa tun so pe o fee to egberun marundinlaaadota baagi iresi lawon gba lodo awon fayawo ti won ko wole lati orileede Benin wa si Naijiria, iyen laarin ojo kefa, osu keji si ojo kefa, osu kejila, odun yii. 

O fikun oro e pe awon iresi yii lo je pe tirela metalaadorin,ni won fi ko o wole lawon gba, eyi ti owo e to bilionu naira. 


Makinde tun fikun oro e pe awon aseyori toun se, ko se e leyin ifowosowopo awon oba alaye ti won paala, atawon eso alaabo yooku, awon ni ko je ki eru naa wo awon lorun ju. 

O ni atileyin tawon ri gba yii tun je ki awon fayawo dinku lakooko yii ju ti ateyin wa lo. 


O so pe nnkan to se pataki ninu e ni pe awon ise tawon n se lo nii se pelu oro aje, eto aabo ati idagbasoke fun orileede yii. 

Leyin to bawon oniroyin soro tan lo wa safihan awon eru ti won ri gba bii epo petiroolu, aloku taya, igbo, oogun oloro Tramadol atawon nnkan mii in. 


O wa seleri pe awon yoo tesiwaju lati gbogun tawon onifayawo ati pe awon yoo maa sise won gege bi ofin ti la a sile fawon. 

No comments:

Post a Comment

Pages