Leke Ọtẹgbẹyẹ ki i sọmọ ẹgbẹ ADC o, irọ lo n pa- Ọnabajo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 3 December 2022

Leke Ọtẹgbẹyẹ ki i sọmọ ẹgbẹ ADC o, irọ lo n pa- ỌnabajoẸgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), tipinlẹ Ogun, ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin ti ẹgbẹ APC n gbe jade lonii pe ọmọ ẹgbẹ ni ADC, ni Leke Ọtẹgbẹyẹ, ti wọn lo darapọ mo APC, wọn ni irọ to jinna si ootọ ni, nitori ọkunrin naa ko figba kan ṣe ẹgbẹ wọn.

 

Ninu atẹjade ti Agbẹnusọ Olumide Ọnabajo, akọwe olupolongo ẹgbẹ ọhun fi sita lo ti rọ Gomina Dapọ Abiọdun, ṣe ni kawọn maa tẹwọgba oun fun ipo gomina lẹẹkeji iyẹn ko le yi ipinnu awọn ti yoo dibo pada fọdun 2023.

 

O sọ pe gbogbo ẹnu loun fi le sọ ọ pe Leke Ọtẹgbẹyẹ ti wọn lo darapọ mọ wọn naa nitori ko le gba ẹbun tiẹ ko figba kankan ṣe pẹlu ADC.

 

Akọwe olupolongo ẹgbẹ yii tun ṣalaye pe bi Leke Ọtẹgbẹyẹ ṣe sọ pe oun ṣepade pọ pẹlu Gomina Abidun, nibi to ti fatilẹyin ẹ han si iṣejọba ẹlẹẹkeji. O ni ko yẹ ki ọkunrin naa ma parọ pe oun jẹ ọmọ ẹgbẹ ADC, nitori ko bawọn ṣẹgbẹ ri.

 

Onabajo sọ pe, " Gbogbo eeyan lo mọ pe akoko ti wọn wa yii, ọdun keresi ti sun mọ etile bẹẹ si ni Gomina n fawọn eeyan to ba gba ko ṣe ẹlẹẹkeji ni ẹbun, nitori idi  ko jọ awọn loju rara’’

 

 

" Bakan naa, ẹni to loun darapọ mọ ẹgbẹ yẹ ko gba nnkan to fẹẹ gba lọwọ Gomina, ko digba to ba parọ pe ọmọ ẹgbẹ APC loun. Bẹẹ  ko fopin si lilo orukọ ẹgbẹ wa lati le sọ ara ẹ di olokiki ti ko nitumọ’’.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ko siye ti Gomina fẹẹ na lati dupo ẹlẹẹkeji, to le yi ọkan awọn eeyan ipinlẹ ogun pada, pẹlu awọn idojukọ ti wọn ti ba pade latigba ti wọn ti dibo yan an wọle lọdun 2023.

 

O ni adari to ba ti mọ pe omi ti fẹẹ tan lẹyin ẹja oun lo maa n wa gbogbo ọna lati ri oju rere wọn.

 


No comments:

Post a Comment

Pages