O tan; Wọn lepe ADC lo n ja ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 3 December 2022

O tan; Wọn lepe ADC lo n ja ẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Ogun




Ọlọrun nikan lo le yanju wahala to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Ogun, nitori nibi ti nnkan de yii, bi wọn ba pade ara wọn ni kọrọ, o ṣee ṣe ki wọn ko ẹsẹ bo ara wọn daadaa, ko si si nnkan mii-in bi ko ṣe bi wọn ṣe le ara wọn kuro ninu ẹgbẹ, eyi tawọn kan sọ pe epe ẹgbẹ oṣelu ADC, lo n ja wọn.

Bi a si ṣe n kọ iroyin yii, ọkan awọn oludije wọn ko ti i balẹ lori ibo to n bọ lọdun 2023, nitori bi wọn ṣe ni ajọ INEC, ko tii gbe orukọ awọn kan jade bẹẹ lo si jẹ pe awọn ti wọn gbe jade ọhun, ẹsẹ wọn n mi, ti wọn si tun fẹsun kan awọn kan ninu wọn pe wọn gbabọde fawọn, nitori ti wọn ṣiṣẹ fawọn oloṣelu mii-in,ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Amọ lọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni wahala naa tun burẹkẹ si nigba ti Micheal Aṣade, alaga  wọn kede pe awọn ti le Doyin Okupe, alakoso agba fun ipolongo  aarẹ wọn, iyẹn Peter Obi. Atawọn mẹwaa mii-in.

Ẹsun ti wọn si fi kan wọn pe wọn ṣe aṣemaṣe nipa ṣiṣe owo ẹgbẹ baṣubaṣu. Nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin ni wọn ti kede pe awọn eeyan naa ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wọn mọ, nitori o ni wọn ṣe awọn nnkan to lodi si ẹgbẹ.

Aṣade yii ati Abayọmi Arabambi, to jẹ akọwe olupolongo fẹgbẹ ọhun ni wọn jọ bawọn oniroyin sọrọ lọjọ naa. Wọn ni gbogbo ọna to yẹ ki Okupe lo lati fi di ọmọ ẹgbẹ nilana ati ofin wọn ni wọn. Wọn lo kuna lati san owo gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ lati nnkan bi oṣu mẹfa sẹyin, ti ko si yẹ ko ri bẹ

Bẹẹ ni wọn tun fẹsun kan lori bi o ṣe nawo ẹgbẹ ti wọn fun lati fi ko awọn eeyan lọ si iwọde ti wọn ṣe nipinlẹ Ọyọ ni inakuna ti ko si so eso rere, ni wọn ba ke si alaga ẹgbẹ naa lapapọ Julius ABURE ati oludije aarẹ wọn, Peter Obi,lati tete wa ẹlomii-in sipo ti ọkunrin naa.

Ṣugbọn siyalẹnu, ṣe ni atẹjade mii-in tun jade lati ilu Abuja pe ti apo awọn ti wọn sọrọ ni wọn sọ ọ si nitori digbi ni awọn wa lẹyin Doyin Okupe, gẹgẹ bi alakoso agba fun ipolongo aarẹ  wọn.

Eyi ni wọn sio n fa lọwọ ti awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu Labour yii tun fi kede lọjọ Furaidee, ọsẹ to kọja, bakan naa pe awọn ti  fofin de akọwe olupolongo ẹgbẹ naa lapapọ, iyẹn Abayọmi Arabambi ati alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Michael Ashade, ati akọwe ẹ, Michael Feyisola.

 

Oloye Lookman Jagun, to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ yii lo kede ọhun, o ni awọn gbe igbesẹ yii lori iwa agabagebe ti wọn sọ pe awọn eeyan ọhun hu si ẹgbẹ. Bẹẹ ni wọn tun sọ pe awọn gba Doyin Okupe bi  ọmọ ẹgbẹ wọn, ti ko si nnkan to le yẹ ẹ.

Bẹẹ lo sọ pe awọn oloye ẹgbẹ naa ti dabaa pe ki awọn oloye ẹgbẹ lapapọ gbe igbimọ kan dide ti yoo wadii awọn ọmọ ẹgbẹ ti wọn fofin de ati Arabambi to jẹ adele akọwe olupolongo ẹgbẹ ọhun, lori awọn akitiyan agabagebe ti wọn ṣe naa.

 Igbakeji alaga naa sọ pe awọn  gbe igbesẹ yii lori awọn ẹsun ọlọkan-ọ-jọkan ti wọn fi kan awọn eeyan ọhun nipa lilẹdi apo pọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun atawọn iwa mii-in. Iyẹn nikan kọ logun ti wọn sọ pe o bawọn ẹgbẹ oṣelu yii finra, nitori titi di akoko yii lọpọ awọn oludije wọn ko ti mọ ibi ti wọn n lọ nipa ibo to n bọ lọdun to n bọ yii.

Bẹẹ lo si jẹ pe idajọ ile-ẹjọ ni wọn duro de, idi niyii to fi jẹ pe ọpọ awọn oludije Labour, ni wọn ko le jade sita lati polongo ibo, ti wọn si n da ẹbi gbogbo ọrọ yii le akọwe olupongo ẹgbẹ wọn lapapọ, to tun ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ naa, Abayọmi Arabambi.

Ni bayii, awọn eeyan ti sọ pe ọrọ naa ko ruju, nitori epe ẹgbẹ oṣelu ADC, ipinlẹ naa lo n ja wọn, nitori wọn ni Labour yii lo fa ara wọn kalẹ fẹgbẹ oṣelu mii-in lati lo wọn, ti wọn fi gbe ẹgbẹ naa lọ sile-ẹjọ, eyi ti wọn lo ti wa nile ẹjọ kotẹmilọrun.

 

No comments:

Post a Comment

Pages