Ijọ Light & Word of Salvation Ministry ṣayẹyẹ ajọdun wọn lara ọtọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 18 December 2022

Ijọ Light & Word of Salvation Ministry ṣayẹyẹ ajọdun wọn lara ọtọOhun to ṣe pataki lati maa dupẹ lọwọ Ọlọrun, ki a si maa fi ẹmi imoore  ẹ han, nitori oore ẹ lori awa ẹda, idi si niyi tawọn ijọ Ọlọrun fi maa n wa ọjọ tabi akoko lati ko awọn ọmọ ijọ atawọn to wa lagbegbe wọn jọ, ti wọn si maa n pe ni ajọdun.

Irufẹ nnkan bẹẹ lo waye ni ijọ imọlẹ ati ọrọ igbala, iyẹn Ijọ Light & Word of Salvation Ministry, to wa ni ojule kẹtadinlogun, Ogbodo, lagbegbe Ogundipẹ, Alapẹrẹ, Ketu, niluu Eko, ṣe  ko awọn eeyan jọ lọjọ Kọkanla, oṣu yii, fun ajọdun nla.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, igba akọkọ kọ ree, ti wọn yoo ṣe ajọdun bẹẹ ṣugbọn tọdun yii tun le kanka. Bo tilẹ jẹ pe ọjọ karun-un, oṣu yii ni wọn ti fi isọji ita gbangba bẹrẹ eto ọhun, ti wọn si pari ẹ, lọjọ kẹjọ.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, ni  wọn ṣe agbayanu orin iyin,oni wakati mejila, nibi tawọn olorin ẹmi ọlọkan-ọ-jọkan, ti wọn fiwe pe ti waa forin da wọn lara ya.

Ọjọ Sannde, to jẹ ọjọ ajọdun ni panbanbari, tawọn ojiṣẹ Ọlọrun jakejado atawọn olorin ẹmi to wa lo ẹbun ti Ọlọrun fun wọn. Nibẹ ni Wolii ati Ajihinrere Oluwafẹmi Jeremiah Okikiọla, to jẹ oludasilẹ ijọ ọhun, to si tun jẹ olugbalejo, ti rọjo adura loriṣiriṣii fawọn to wa nibẹ lọjọ naa.

Bakan naa ni gbajumọ olorin ẹmi nni, Ajihinrere Dokita Rotimi Okikiọla Onimọlẹ, tọpọ awọn eeyan mọ si Ọba Àrà, naa ti lo ẹbun orin lati fi dupẹ lọwọ Ọlọrun.

Ọpọ awọn to wa nibẹ ni wọn si jẹri agbara Ọlọrun ninu ijọ naa, eyi ti wọn ni Ọlọrun lo Wolii Oluwafẹmi Okikiọla, fawọn, tawọn si ri ipa ẹ ninu aye wọn.


1 comment:

Pages