Mo sese bere ise iranse ni-Wolii Ogundipe Genesis - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 18 December 2022

Mo sese bere ise iranse ni-Wolii Ogundipe GenesisOjiṣẹ Ọlọrun Isreal Ọladele Ogundipẹ, to jẹ oludasilẹ  ijọ Genesis Celestistial Church Of Christ, to wa ni Alakukọ, niluu Eko ti sọ pe gbogbo iṣẹ iranṣẹ toun ṣe kaakiri pe oun ko ti i bẹrẹ rara, oun ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni.

Wolii Ọlọrun naa sọrọ yii lakooko to n fọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin, nibi ayẹyẹ ajọdun ijọ naa to waye lonii. O sọ pe Loootọ ni oju ti ri amọ oun dupẹ lọwọ Ọlọrun, nitori ki i ṣe nitori owo loun ṣe gba iṣẹ naa.

Gẹnẹsisi tun sọ pe, ‘’Emi o ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ rara, nitori pe  mi o ṣiṣẹ iranṣẹ nitori owo, nitori ni mi o ki i ṣọ pe ki eeyan lọọ mu iye bayii wa, gbogbo nnkan ti ẹ ri ni agbegbe yii, awọn kan wa ti wọn maa n wa lati ilu oyinbo, bi wọn ṣe maa n wa lọdọọdun niyẹn’’.

‘’Gbogbo ootẹli to wa laduugbo yii ni wọn gba, awọn ni wọn sanwo ara wọn.Mi o ti bẹrẹ o, nitori ọkan wa ti mo bẹrẹ lati ọsẹ to kọja lọhun, mo lọ si ibudokọ,awọn tawọn eeyan maa n pe ni ọmọọta, mo ni wọn ki i ṣe bẹẹ’’.

‘’Eyi to ba faye ẹ fun Ọlọrun, ko ba jẹ ẹlẹsin musulumi, ki o lọ ma sin Ọlọrun ẹ, ẹni to ba fẹẹ kọṣẹ ninu wọn, ẹ jẹ ko lọ maa kọ.Eyi to ba si fẹẹ ma ta ọja, nnkan ta a ba ri, a maa fi ran an lọwọ,idi ti mo fi sọ pe mi o bẹrẹ niyẹn. Bibeli mi ni mo gbagbọ’’.

‘’Ṣugbọn iṣẹ iranṣẹ ti mo gba, o nii ṣe pẹlu ifẹ ati fifi ẹmi imoore inu ẹkun ti Ọlọrun ti mu mi kuro, ti mo ba sun ẹkun naa, omije ayọ. Nitori bi a ba si wa laaye, ọpọlọpọ irin ni a maa rin, ninu ka fọwọ la igbo, tabi kawọn eeyan kọ wa bi wọn ṣe ẹgun la a, gbogbo bo ṣe wu ko ri, ẹ ṣaa jẹ ki a ma lọ’’.

Bakan naa lo tun lo akoko naa lati sọ fawọn ti wọn maa n ṣe idajọ awọn iranṣẹ Ọlọrun, nipa bi wọn ṣe n lo mọto ati ọkọ ofurufu ti ara wọn, ki wọn dẹkun, o ni bo tilẹ jẹ pe oun ki isọ nipa aṣiṣe ẹnikẹni.

O sọ pe, ‘Gbogbo nnkan laye yii, ẹ ma jẹ ki a ri aṣiṣẹ ẹnikẹni,bi a ba ri ẹni to n ṣe nnkan ti ko dara, ẹ jẹ ki a ma ṣatunṣe ẹ. Ẹyin naa ti ẹ jẹ oniroyin bi ẹ ba sọ nipa aṣiiri ẹlomii-in, ṣe ẹ le gba. Bi emi o tiẹ lepa ẹ, e wo waa ni ki n sọrọ nipa ẹ’’.

‘’Bibeli sọ fun wa pe ogo ikẹyin yoo pọ ju ti iwaju lọ, awọn ti ko mọ Ọlọrun, wọn n lo, awọn ti ko mọ-ọn rara, wọn n lo.Ẹ tiẹ sọrọ mọto, bi ẹ ko ba ri mọto bawo ni ẹ ṣe fẹẹ debi? Nigba aye Jesu ko si mọto, nigba aye ẹ, ko si ọkọ ofurufu’’.

‘Igba ẹ ko si gbogbo nnkan ti ẹ darukọ bẹẹ naa ni ko si fooni ti ẹ gbe dani. Iyẹn ni Jesu ṣiṣẹ, nitori ki awa ma baa ma ṣíṣẹ̀ẹ́. Eyi to ju nibẹ ni pe ki a ma lepa awọn nnkan ni alepa ju, gbogbo nnkan ti a ba ṣe, ki a maa ranti ọla’.

‘’Emi o ki i ba eeyan sọ pe ẹni yii ko dara, ẹni yii dara, iwọ ni ko beere ayanmọ to wa lo nile aye, bi o ba le ṣe e ṣe, ki lo de ti a ki fi i beere iya teeyan jẹ, ki o to de oke, to jẹ pe nigba to ba goke tan an, ni a maa wadii bp ṣe de oke’.

‘’Loootọ ẹni to gbaṣẹ iranṣẹ wa bẹẹ ni ẹni to fẹẹ fi jẹun wa. Ọlọrun lo mọ onikaluku ni mi o ṣe le dajọ ẹnikẹni. Emi aimoye oore tawọn eeyan ti ṣe fun mi laimọye ọna, iru ileewe kan wa nibẹ yẹn, emi o tii da a silẹ o, ti Ọlọrun ba sọ pe mo maa ni,  a maa ni fun ṣọọṣi ni.

‘’A maa jẹ kawọn ọmọ ijọ lọ sibẹ, bo ba le ṣeeṣe, wọn ko nii sanwo, tawọn eeyan ba le ṣe agbatẹru ẹ, ṣugbọn ti ko ba si, wọn yoo maa san iwọnba. Nitori emi tiẹ ẹ n wo yii, mi o rowo lọ sileewe, mi o rwow ṣe idanwo oniwe mẹwaa, mi o rowo lọ yunifasiti, nitori idi eyi, mi o fẹẹ ṣe idajọ ẹnikẹni.

‘’Gbogbo awa ta a  n wo yii, ko sẹni to le sọ ibi ti adura yoo ti gba, awọn eeyan kan wa to jẹ pe ko mọ ibi ti wọn sin baba ẹ kẹrin si.Ile ti wọn mọ si ile oloṣi, Ọlọrun fun mi lati kọ. Ẹ ma jẹ ka dajọ ẹlẹjọ, ẹ jẹ ka wo ipa nnkan ti awa le ṣe’’

Nibi ajọdun to waye naa ni Ebenezer Obey ti forin da awọn eeyan lọla bẹẹ  naa.Mega 99 naa tun dabira. 


No comments:

Post a Comment

Pages