Ojogbon Olagoke gba ijoba lamoran lori eko ibi ikawe lawon ileewe - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 19 December 2022

Ojogbon Olagoke gba ijoba lamoran lori eko ibi ikawe lawon ileewe




Ojogbon Sabit Ariyo Olagoke, oludasile ileewe musulumi nni Sharafaudeen, ti ro ijoba lati da eko nipa ikawe pada sawon ileewe kaakiri jakejado orileede yii. 

O ni eyi yoo je kawon omo naa tun ni imo igbe nnkan sori ti yoo si wulo fun won lojo iwaju. 

Olori elesin naa to tun je mogaji Ogun Elu, Safe Alaasa, soro naa lakooko to n bawon si ile ikawe eyi ti ileese redio ipinle  Oyo iyen BCOS sagbateru e. 

O fikun oro e pe pataki ibi ikawe je ta a toju awon ise iwadii fun kika paapaa julo awon asa wa, o tun wa fun isamulo opolo ati iriri fawon to fe kowe tabi sise awon iwadii. 

Ojogbon Olagoke tun sapejuwe ibi ikawe gege bi akolo ile ogbon, nibi ti imo ti saaba maa n jade. 

O waa so pe bi a ba le da eko yoo pada yoo tun je ko gbooro si lawujo, o waa fi bo se pade iyawo e ni yara ibi ikawe lodum 1973, se apejuwe. 


Ojogbon waa soju abe niko pe yara ibi ikawe nikan nibi ta a le toju awon iroyin pamo fawon iran tp n bo ati fun idagbasoke ise iwadii


Bakan naa ni Ojogbon Yemi Farounbi, so nibi ayeye naa ti won fi sori ose awon oniroyin ti eka BCOS, pe oun to se pataki ni ki won ni awon yara ikawe ti won yoo maa ko awon iwe ati iroyin pamo si.

Nibi ayeye naa tun ni won ti fi ami eye Baba Isale da Ojogbon Olagoke lola lati  fi emi imoore han, lori bo se ko yara ibi ikawe naa fun won. 



No comments:

Post a Comment

Pages