Se ni inu awon omode dun senken nigba tijoba ipinle Ogun sajoyo odun keresi pelu won, nibi ti won ti fun egberun kan won lebun odun.Ayeye eyi ti won pe ni Ariya ori omi fawon omode eyi tijoba ipinle Ogun nipase ileese to n ri si asa ibile ati irinajo afe sagbateru e, ni won ti pa awon omode naa lerin.
Awon omode yii ti ojo ori won ko ju odun meji si mejidinlogun lo ni won derin pa eeke won ti won fun lebum odun naa. Paapaa julo awon to se daadaa ninu ijo jijo atawon idije olokan-o-jokan.
Nigba to n soro nibi ayeye naa, Onarebu Adijat Adeleye-Oladapo, to je komisanna foro asa ati irimajo afe nipinle naa, so pe eto naa wa fawon omode to wa ni agbegbe Abeokuta lati fi mu inu won dun paapaa fun ti isinmi ileewe ti won wa lakooko yii. Ki won si maa fi se iranti.
Gege bo se wi, o ni eyi je okan lara nnkan ti isakoko to wa lode fi safihan ife sawon omode paapaa lakooko odun keresi. O ni ijoba gan an mo funra won pe odun ko tii dun ti won ko se nnkan tinu awon omo yoo fi dun, ki won si fi ife han won
Awon omo naa fi emi imoore han fun bijoba ipinle Ogun se mu inu won dun,
Emmanuel Nwabusi, Kolade Adegoke ati Esther Fagbenro, ti won soro loruko awon yooku won dupe gidi lowo ijoba fun bi won se mu inu won dun fodun naa.
No comments:
Post a Comment