Ẹ sọ agbara igbagbọ yin dọtun, ki ẹ si fi akoko ọdun keresi gbadura fun alaafia ibo to n bọ- Sẹnetọ Adeọla Yayi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 24 December 2022

Ẹ sọ agbara igbagbọ yin dọtun, ki ẹ si fi akoko ọdun keresi gbadura fun alaafia ibo to n bọ- Sẹnetọ Adeọla Yayi



 

 

Sẹnetọ Solomon Adeọla, alaga igbimọ nipa eto isuna nile igbimọ aṣofin niluu Abuja, ti rọ gbogbo awọn onigbagbọ lorileede yii lati lo akoko ọdun keresi to wọle wẹrẹ yii lati fi sọ igbagbọ wọn ọtun ninu Jesu Kristi, ti Nasarẹti, ki wọn si fi gbadura ki ibo to n bọ lọdun to n bọ yii ko waye nirọwọ-rọsẹ.

 

Ninu atẹjade ti aṣofin ọhun sọwọ si, ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ oludamọran pataki fun eto iroyin ẹ gbe jade lati fi ki gbogbo ọmọlẹyin Kristi ku ti ayẹyẹ ọdun keresi, to wọle yii, lo ti ṣalaye pataki nnkan ti ọdun naa duro fun gẹgẹ bi ayajọ pe a bi Olugbala wa saye, lo tun ti sọ pe bi a ṣe n ṣajọyọ naa bẹẹ naa ki a ma nireti fun ọjọ iwaju pe yoo dara fun igbala awọn eeyan.

 

Aṣofin Adeọla, to n dije dupo ninu ibo to n bọ fun ipo aṣofun fun ẹkun Ogun West tun sọ pe, “ Mo fẹẹ rọ gbogbo awọn onigbagbọ, lati ma ṣe lo ọdun keresi fun igbadn lasan bi ko ṣe alti fi wa oju rere Ọlọrun, fun irọrun ati Alafia fun ọjọ iwaju orileede yii. Mo si fẹẹ ki a lo anfaani naa lati fi gbadura fun igba ọtun pẹlu paapaa julọ fun ibo to n bọ lọna’’

 

O ni bo tilẹ jẹ awọn ọmọ orileede yii n koju awọn ipenija lori ọrọ aje wa ṣugbọn o gba wọn nimọran lati ṣe suuru, ki wọn si figbagbọ wọn han ninu Kristi, pẹlu idaniloju pe ohun gbogbo n bọ wa rọrun, ti idagbasoke yoo si de ba onikaluku wa lawujọ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages