Ẹ jẹ ka fi akoko ọdun keresi gbadura fun alaafia ati igbeaye irọrun orileede yii- Ọnarebu Rasak Eyiowuawi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 24 December 2022

Ẹ jẹ ka fi akoko ọdun keresi gbadura fun alaafia ati igbeaye irọrun orileede yii- Ọnarebu Rasak Eyiowuawi



Ọnarebu Rasak Ọlaṣupọ Eyiowuawi, to n dije dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu Afican Democratic Congress,ADC, fun agbegbe Abẹokuta North, Ọdẹda ati Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ti ba gbogbo ọmọ ipinlẹ naa ṣajọyọ ọdun keresi to wa nita bayii.

Ninu iṣẹ ọdun ti ọkunrin naa fi sita, lo ti sọ kọkọ bawọn eeyan dupẹ pe wọn ri ọdun yii layọ ati alaafia, nitori ọpọ ta a jọ ṣe ọdun to kọja, ni wọn ko si laye mọ,ṣugbọn ti Ọlọrun fun wa ni ore ọfẹ ri ọdun ti ọdun yii ni ayọ ati alaafia.

 Ọkunrin yii wa gbogbo awọn eeyan lamọran pe ki wọn ṣe ọdun naa niwọtunwọnsi, ki wọn si lo akoko naa lati fi gbadura fun igbe aye alaafia ati irọrun fun orileedde yii, nitori o loun nigbagbọ pe gbogbo ẹ s n bọ wa dara.

Bakan naa ni ọkunrin yii tun lo anfaani yii lati fi ọkan awọn araalu paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC, balẹ, nitori pe oun nigbagbọ pe awọn yoo jawe olubori ninu ẹjọ kotẹmilọrun tawọn pe,ti gbogbo nnkan yoo si pada si ni lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Eyiowuawi tun fikun pe ẹru lo n bawọn alatako oloṣelu kan ti wọn fi n ṣe nnkan ti wọn ṣe, nitori wọn ti mọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ lọdun 2023, o waa ni ki wọn ma ṣe rẹwẹsi rara, ki wọn si maa fi adura ran wọn lọwọ pẹlu igbagbọ pe o ti ṣee ṣe.


No comments:

Post a Comment

Pages