Ẹ ma ṣọ ireti nu, bẹẹ ni ẹ ma bẹru, ẹ fi ifẹ han lakooko ọdun keresi- Ọtẹgbẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 24 December 2022

Ẹ ma ṣọ ireti nu, bẹẹ ni ẹ ma bẹru, ẹ fi ifẹ han lakooko ọdun keresi- Ọtẹgbẹyẹ



 Amofin Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije fun ipo gomina, labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ninu ibo to n bọ lọdun 2023, ti pe gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati ma ṣe sọ ireti wọn nu nitori ireti igbala bẹrẹ latigba ti wọn ti bi Jesu Kristi saye.

 

Ninu atẹjade tawọn ikọ iroyin ọkunrin naa fi sita, eyi to fọwọ si, lo ti ki awọn eeyan  paapaa julọ awọn ọmọ orileede Naijiria, ku oriire ọdun keresi ki wọn si gba gẹgẹ bi ọdun ireti.

 

O sọ pe, "Ki i ṣe ariyanjiyan rara, ọdun keresi tumọ si ọdun ayọ, idunnu, igbadun ati awada. Bi mo si n ṣe e pẹlu awọn eeyan mi ninu ajọyọ nla, mo fẹẹ fi akoko ọhun ran awọn eeyan wa leti ẹkọ nla ta a ri di mu ninu ayajọ ọdun keresi gẹgẹ bi ireti ninu Jesu fun igbala ọkan’’.

 

" Mo fi gbogbo ọkan mi ki gbogbo ọmọ Naijiria, awọn onigbagbọ ati gbogbo ọmọ bibi ipinlẹ Ogun patapata ku ọdun. Ko si nnkan to le mu kawọn eeyan wa maa bẹru tabi sọ ireti nu nitori akoko igbala wa ti fẹẹ sunmọ etile’’

 

 

" Mo gbadura pe ki ki Ọlọrun fi akoko ayọ ta a wa ninu ẹ yii kun inu ọkan wa,ki a si gbe wọ inu ọdun tuntun layọ ati alaafia. Mo tun wa rọ wa Iati ṣe gbogbo nnkan niwọntunwọnsi, ki a si akoko silẹ fun adura nitori awọn ipenija to n koju wa. Ohun to waa ṣe pataki julọ ni pe ki a fi ifẹ han si ara wa’’

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages