Oludije fun ipo aṣoju- ṣofin, fun agbegbe Abẹokuta South, labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Tolulọpẹ Olufikayọ Phillips, ti rọ awọn kristẹẹni, paapaa julọ awọn ọmọ orileede yii, lati lo akoko ọdun tuntun ta a ṣẹṣẹ wọ yii fun adura oju rere lati ọdọ Ọlọrun wa fun ibo to n bọ lọna.
Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita, to fi ki gbogbo awọn eeyan Abẹokuta South atawọn ọmọ orileede yii lapapọ ku ayẹyẹ ọdun tuntun, lo ti sọ pe ohun to ṣe pataki ni pe ki a lo akoko ọdun naa lati fi bẹ Ọlọrun ko ṣi oju rere rẹ fun wa, ki ibo to n bọ naa le lọ nirọwọ rọsẹ.
O sọ pe gbogbo wa la mọ pe ibo gbogbogboo ti sunmọ etile lati yan awọn adari tuntun ti yoo tukọ orileede wa fọdun mẹrin-in mii-in. Oju rere Ọlọrun nikan lo sọ pe o le tọ wa sọna lati fi le ni adari rere.
Bakan naa lo tun rọ awọn araalu lati ṣe ọdun naa niwọntun wọnsi, ki wọn ma ṣe ju agbara wọn lọ, bẹẹ ni ki wọn si fi ifẹ han si ọmọnikeji wọn ninu ọdun naa, nitori ifẹ ni Ọlọrun n fẹ laarin wa.
Atẹjade ọhun lọ bayii, ‘’ Mo ki gbogbo awọn eeyan mi ni Abẹokuta South, paapaa julọ nipinlẹ Ogun, ku ewu ọdun tuntun, ẹmi waa yoo ṣe pupọ lorilẹ. Mo fẹẹ ki ẹ fi akokoo yii fi gbadura si Ọlọrun lati ṣi oju rere ẹ fun wa paapaa fun ibo ti n bọ lọna yii’’
Nitori pe oju rere pẹlu itọsọna Ọlọrun lo le jẹ ka ni dibo yan awọn adari rere ninu ibo yii. Loootọ, ni a n koju ọpọ ipenija lorileede yii ṣugbọn mo nigbagbọ pe asiko ti ti Ọlọrun fẹẹ mu wa bori ipenija ọhun, ti gbogbo nnkan yoo si ma lọ, bo ṣe yẹ ko lọ’’
Oludije naa tun akoko yii lati ran awọn eeyan agbegbe Abeẹokuta South leti lati fi ibo wọn gbe oun wọle gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin wọn niluu Abuja. O ni oun nigbagbọ pe awọn eeyan oun ko ni doju ti oun ati pe gbogbo ileri toun ṣe loun yoo mu ṣẹ lagbara Ọlọrun, bi wọn ba le dibo foun ninu ibo naa
No comments:
Post a Comment