Biyi Ọtẹgbẹyẹ ni kawọn eeyan ipinlẹ Ogun eeyan ni aforiti lati bori ipenija - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 31 December 2022

Biyi Ọtẹgbẹyẹ ni kawọn eeyan ipinlẹ Ogun eeyan ni aforiti lati bori ipenija

 Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ,oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti rọ gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ naa lati ṣiṣẹ takuntakun, ki wọn si ni aforiti lati le bori awọn ipenija lọdun 2023.

 

Ninu iṣẹ ikinni ku ọdun to fi sita lati bawọn eeyan ipinlẹ ọhun ṣajọyọ ọdun tuntun lo ti sọ bẹẹ, bẹẹ lo tun ke si wọn lati mura ki  wọn si jẹ ki aya wọn ko le lawọn akoko to le koko yii.

 

O mu ọrọ ẹ jade ninu iwe ti ara Amẹrika kan, Robert Harold Schuller, kọ nibi to ti sọ pe igba iṣoro ki i lopin amọ awọn to ba laya ma duro ti. O ni awọn eeyan to ba  duro gbọingbọin ni yoo bori ere ije ninu aye yii.

 

 O rọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun rere lati fi ifẹ han si akẹgbẹ wọn, awọn ti Ọlọrun ba bunkun fun ki wọn ranti awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ. Bẹẹ lo tun rọ wọn lati yẹra fawọn nnkan to le da wahala silẹ, to le maa mu wọn sa fun awọn alaabo ilu.

 

O waa gbadura aabo ati iṣọ Ọlọrun fawọn eeyan ipinlẹ naa ti wọn yoo fi la ọdun tuntun yii ja, pẹlu adura pe ọdun naa yoo tu gbogbo tile-toko lara.


No comments:

Post a Comment

Pages