Ẹ fọkanbalẹ, digbi lawọn oludije ẹgbẹ oṣelu ADC wa- Olumide Ọnabajo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 2 December 2022

Ẹ fọkanbalẹ, digbi lawọn oludije ẹgbẹ oṣelu ADC wa- Olumide Ọnabajo



 

Agbẹjọro Olumide Ọnabajọ, to jẹ akọwe olupolongo fẹgbẹ oṣelu African Democtratic Congress, ADC, nìpinlẹ Ogun, ti fọkan awọn araalu paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun balẹ pe didun ni ọsan yoo so laipẹ ati pe digbi lawọn oludije naa, ti ẹsẹ wọn ko mi lailai

 

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita, lo ti sọ pe igbẹjọ to waye lọsẹ to kọja ọhun, ko mu ifasẹyin bawọn oludije ọhun nireti pe ayọ ni wọn yoo ba bọ ninu ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe, nitori gbogbo awọn ẹri to ti wa nilẹ.

 

Akọwe olupolongo ọhun tun tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko mọ nipa atako tawọn kan gbe dide latigba ti Gomina tẹlẹ nipinlẹ naa, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ti jade sita gbangba lati ṣatilẹyin fun Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti wọn si n gbe oriṣiriṣi jade.

 

O ni ti wọn si n lo awọn ọba alaye kan,ti wọn lo owo ijọba, ti wọn ko fẹẹ jẹ ki iṣẹ ti Ọlọrun ti pari waa si imuṣẹ, o ni pẹlu pe wọn n ko ara wọn jọ papọ lati ditẹ,eyi to mu ki igbẹjọ to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, sibẹ o ni o dawọn loju bo ogo ti n jẹ ti Ọlọrun ẹgbẹ gbogbo awọn oludije ẹgbẹ ADC ni yoo kopa nibi ibo to n bọ lọdun 2003.

 

Akọwe olùponlongo ẹgbẹ naa tun sọ pe, ‘ Gbogbo eeyan lo ti mọ pe ogun nla ni ẹgbẹ oṣelu ADC, jẹ fun ijọba to wa lode nipinlẹ yii, nitori idi ẹ ni wọn ko fi le sun, ti ara wọn ko balẹ mọ, ti wọn si mọ pe oke ti wọn ko le ṣi nidii ni Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ ati Alaaji Tunde Awonuga, ti wọn jẹ oludije gomina sati igbakeji ẹ.

 

O ṣalaye siwaju pe laipẹ yii, ni ile ẹjọ kotẹmilọrun to ni Port Harcourt, tun tan imọlẹ si fun gbogbo ọmọ orileede yii pe ko si ẹgbẹ oṣelu kan to ni agbara lati gbe ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ ẹ lọ si kootu lori ọrọ ibo abẹle,itunmọ ni pe ẹgbẹ oṣelu Labour  ko ni agbara lati gbe wọn lọ sile ẹjọ.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ‘’ ibo abẹle ẹgbẹ wa ki i ṣe pe a kan ṣe lasan bi ko ṣe pe bi ofin ati ilana ṣe la a silẹ ati pe ajọ INEC tun mojuto pẹlu. Eyi to da mi loju pe gbogbo awọn nnkan wọnyii nile ẹjọ kotẹmilọrun yoo fi da awọn oludije wa pada’’.

 

O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati ma ṣe mi kan raran ki wọn si wa niṣọkan nitori pe orin iṣẹgun ni wọn yoo kọ nigbẹyin.

 


1 comment:

Pages