Ẹru lo n bawọn, a maa bori wọn nile-ẹjọ kotẹmilọrun- Awọn oludije ile igbimọ aṣofin ADC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 26 November 2022

Ẹru lo n bawọn, a maa bori wọn nile-ẹjọ kotẹmilọrun- Awọn oludije ile igbimọ aṣofin ADC
 

Awọn oludije ile igbimọ aṣofin ti abẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti sọ fawọn alatilẹyin wọn paapaa julọ awọn araalu lati fi ọkan wọn balẹ lori abajade idajọ to waye nile-ẹjọ ijọba apapọ, niluu Abẹokuta, lana-an, nitori awọn ti ko fẹẹ jẹ ki idibo to n bọ naa waye nirọwọ-rọsẹ, lo wa nidii ẹ.

 

Ninu atẹjade kan to fi sita, lo ti sọ pe ibẹru ko si fun ọmọ Ọlọrun, nitori awọn nigbagbọ pe ile-ẹjọ kotẹmilọrun tawọn n lọ lawọn yoo ti gba ẹtọ wọn pada, eyi to sọ pe ko ni pẹ mọ.

 

Awọn Ọnarebu naa tun sọ pe awọn lo akoko yii lati rọ awọn alatilẹyin wọn pe ki wọn fọkanbalẹ, ki wọn si tẹsiwaju lati maa tan imọlẹ ẹgbẹ yii,titi iroyin ayọ tawọn n reti yoo fi de, to si mu dawọn loju pe didun lọsan yoo so nigbẹyin.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages