Mi o bẹru lati koju Sanwo-Olu fun ibo gomina- Tọpẹ Abdulrasaq Balogun, AA - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 2 December 2022

Mi o bẹru lati koju Sanwo-Olu fun ibo gomina- Tọpẹ Abdulrasaq Balogun, AA
Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, nipinlẹ Eko, Tọpẹ Abdulrasaq Balogun, ti mu da gbogbo ọmọ ipinlẹ naa loju pe jijade dupo oun, ki i ṣe lati foribalẹ fẹnikẹni pe oun ko kopa mọ, bi ko ṣe lati jade dupo, ki oun si wọle ninu ibo naa to yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023.

Oludije naa sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin wa fọrọwerọ, o ni bo tillẹ jẹ pe oju alainikanṣe lawọn araalu fi n wo awọn oludije kan ti wọn jade, nitori pe wọn tun le sọ pe awọn fẹẹ ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu kan, amọ ti toun ko ri bẹẹ rara, idi niyii toun fi ojoojumọ polongo lati jẹ ki wọn mọ pe aoun ṣetan lati gbajọba lọwọ APC, ti wọn wa nijọba bayii.

O ṣalaye pe pẹlu awọn iriri toun ti ni nidi oṣelu lati nnkan bi ogun ọdun o le diẹ sẹyin o ti to foun lati fi le di gomina, ki oun si gbajọba, nitori ijọba to wa lode yii ti su awọn araalu, gbogbo wọn ni wọn si n pariwo pe ki ayipada rere deba.

Tọpẹ tun sọ pe,  ‘’Pẹlu awọn esi gidi ti mo mu jade nileewe, ti mo si tun gba ẹbun, bẹẹ ni mo tun ni anfaani lati kọ ẹkọ nipa oṣelu lọdọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko, Alaaji Lateef Jakande, mo ranti pe a maa n lọ sile wọn, ti si ni ọpọ iriri, eyi ta a fi n dari awọn araalu’’

Oludije ọhun to jade nileewe giga yunifasiti Nsukka, nibi to ti kọ ẹkọ nipa Computa ati National Open University NOUn, fi kun ọrọ ẹ pe gẹgẹ bi awọn erongba oun fawọn araalu, iyẹn manifesto, lo ti ni o kere tan awọn egberun lona irinwo le ni aadọta eeyan ni iṣẹ yoo wa fun, ti wọn yoo maa ri ọwọ lọ si ẹnu.

Erongba ọhun to pe ni ‘’ Rebirth, lo ti ṣalaye pe awọn ti ko oriṣiriṣii nnkan jọ ni ọna ti yoo mu idẹrun ba awọn eeyan ipinlẹ Eko, ti yoo si fopin si igbe aye oṣi oun ipọnju. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti jọ wa ninu ẹgbẹ kan naa tẹlẹ, tawọn si kuro nibẹ, tawọn tun pada, ko to di oun wa ni AA, gbogbo awọn ete wọn.

Tọpẹ ni. ‘’ A jọ wa ni ACN tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti wọn huwa familete n tutọ lo mu wa kuro nibọ bọ si ẹgbẹ oṣelu CPC, nibi ti Buhari wa tẹlẹ, nigba  to ya ni wọn pe wa pada ta a si jọ wa ni APC, amọ ti iwa wọn ko yipada, ni mo ṣe kuro nibẹ, ti mo si wa ni AA, ti mo si mọ pe emi ni maa wọle lọdun 2023.

O ni loootọ bo tilẹ jẹ pe Ọlọrun bunkun ipinlẹ Eko pupọ ṣugbọn imọtara ẹni nikan lo n ba awọn aṣiwaju jẹ, ti wọn ko si ni ifẹ ọmọ ipinlẹ kankan ninu. O waa lo akoko naa lati sọ fun Gomina Babajide Sanwo-Olu, lati maa palẹ ẹru ẹ mọ, nitori igba diẹ lo ku fun un.

 


No comments:

Post a Comment

Pages