Ṣẹgun Ṣowumi ni orileede yii nilo Ọbasanjọ lakooko yii - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 5 November 2022

Ṣẹgun Ṣowumi ni orileede yii nilo Ọbasanjọ lakooko yii


Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, ti rọ aarẹ tẹlẹ lorileede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ lati ma ṣe wo wọn niran fun ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023, nitori pe awoọ eeyan nilo ọpọlọ ati iriri ẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti, to kọja yii lo ti sọ pe ki aarẹ naa tẹlẹ ma ṣe rẹwẹsi nitori awọn ọmọ orileede yii ṣi nilo amọran ẹ lati fi le wa ojutu si ayipada awọn aṣaaju ninu ibo to n bọ naa.

Oludije ọhun tun tẹsiwaju pe oun dupẹ fun ọna ti Ọbasanjọ gba lati fi yanju awọn wahala to n koju ilẹ Afrika paapaa julọ orileede Ethiopia, to ṣẹṣẹ yanju laipẹ yii, o ni ohun iwuri nla lo jẹ ati aṣeyọri gidi.

Ṣowumi tun sọ pe, ‘ Inu mi dun lati darapọ mọ miliọnu awọn eeyan paapaa ni orileeede Ethiopian, lati dupẹ lọwọ Baba Obasanjo, fun erongba wọn lati yanju wahala to n waye nibẹ lati nnkan bi ọpọ ọdun sẹyin, mo ranti pe ẹ ti ṣe iru nnkan bẹẹ ni Namibia ati Zimbabwean. Baba, ẹ ti kọ awọn eeyan lẹkọọ nipa igbesi aye paapaa julọ lori pataki ẹmi ọmọniyan’’.

O waa sọ pe pẹlu aṣeyọri ti Ọbasanjọ ṣe ni Ethiopia, o tun wa ke si lati ma ṣe gbagbe orileede yii nipa idojukọ ijangbara lakooko ti ibo gbogbogboo sunmọ etile. O sọ pe oun nigbagbọ pe nnkan toun sọ yii yoo ye Ọbasanjọ nipa bi wọn yoo ṣe wa ojutu si isoro to koju wa ni eto aabo ati ọrọ aje lapap. O waa gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun wọn ni ẹmi gigun ati alaafia lorilẹ eepẹ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages