Wọ́n ni Macgregor, ọba tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn kó tọ́ọ̀gì wọ ilu orile Ilawọ. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 5 November 2022

Wọ́n ni Macgregor, ọba tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn kó tọ́ọ̀gì wọ ilu orile Ilawọ.


Irọ ni wọn pa

Titi di akoko ta a wa yii, inu ibẹru bojo lawọn eeyan Ilawọ nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, wa bayii, nitori bi wọn ṣe fẹsun kan ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ darukọ ẹ, Ọba Alexander Oluṣẹgun Macgregor, pe o ko awọn tọọgi wọnu ilu naa, ti wọn si sa awọn eeyan yannayanna.

Bo tilẹ jẹ pe a gbọ pe ọwọ ọlọpaa Adatan, niluu Abẹokuta, ti tẹ marun-un, ninu awọn ti wọn ṣiṣẹ ọhun, ti wọn si ni wọn yoo foju bale ẹjọ sibẹ ṣe ni ọkan awọn ara abule ọhun ko balẹ, nitori wọn ni awọn ko mọ nnkan to tun le ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bi iwadii wa, wọn ni ọrọ ọlọbade ti wọn ni awọn ijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ ṣeto ẹ, ti wọn lo jẹ awuruju, ti wọn darukọ Macgregor gẹgẹ bi ọba tuntun amọ ti wọn ni ko tẹ ilu lọrun, ti wọn si fi ẹhonu wọn han Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ ati Oṣilẹ Oke-Ọna, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo pẹlu Ijọba ipinlẹ Ogun, lo mu kawọn eeyan ọba naa lọ bawọn to ṣewọde lati abule ti wọn si sawọn ladaa.


Ninu fidio ti wọn fihan wa lẹyin ti wọn sawọn ara abule naa ladaa ni awọn ara abule ti n pariwo pe ki wọn gba awọn o. Ọkan lara awọn eeyan ọhun to ba oniroyin wa sọrọ, sọ pe, ‘’Lẹyin ti wọn ṣe awuruju ipade ti wọn ṣe, ni ẹlẹgun mẹfa, awọn ara abule lati  Orile Ilawọ  pẹlu awọn Baalẹ mẹtalelọgọta, ni wọn lọọ fi ẹhonu wọn han, wọn wa si ọdọ Alake, pe awọn ko fẹ Macgregor, nitori ki i ṣe ọmọ bibi Ilawọ, ko wa lati abule, ko ni abule laarin wa, to ba ni ko wa sọ nigbangba, ibi to ti wa, nnkan tawọn ijọba ibilẹ lọọ ṣe pẹlu ọgbọn alukọrọmi, ko ṣiṣẹ, awọn lawọn gbe nibẹ’’

A lọ sọdọ Oṣilẹ, bẹẹ naa ni a  tun lọ si ileeṣẹ to n ri  si ọlọbade  ati ọdọ Gomina, iyẹn lo faa to fi jẹ pe ọsẹ to tẹle, ni Macgregor  ṣe ẹhonu tiẹ, nigba to di aarọ Satide, ni wọn sọ pe gbogbo awọn to ṣe ẹhọnu akọkọ, awọn yoo wa wọn jade,  ti wọn si se bẹẹ ti wọn wo ilu wa, ti wọn ṣa wọn ladaa, to si jẹ pe wọn fẹẹ ku’’.

‘’Ilu gbera lati lọ toju awọn ti wọn ṣa, lati bi ọjọ Monde,  ni awọn eeyan Macgrgor, tun ti gbiyanju  lati gba awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi yẹn silẹ, nitori wọn mu marun-un,  ninu wọn, bẹẹ ni wọn tun ti lọọ n bawọn ti ṣa pe ki wọn maa sẹjọ mọ amọ ọlọpaa Adatan, ko gba fun wọn,  won ti gbe wọn lọ sile ẹjọ’’.

ni

Ninu ọrọ Oloye Lawrence  Lawrence Olufẹmi Atanda Ogunsanya, ọkan lara awọn oludije ọba niluu naa, o sọ pe,  Nigba  ti mo nifẹẹ lati jọba, mo wa si ilu, nitori pe awọn babanla wa, wa lara awọn to ja fun ominira Ẹgba nigba naa. Wọn ni ki n to le jẹ ọba , mo gbodọ ni awọtẹlẹ, ki lo n jẹ bẹẹ, wọn ni mo gbọdọ joye ilu ti wọn si foun jẹ Akọgun’’. 

O ni lẹyin toun jẹ ẹ tan ni wọn sọ foun pe oun lẹtọọ lati dupo ọba, awọn  marun-un lawọn gba fọọmu. Tawọn ilu si mu forukọ awọn afọbajẹ ti wọn yoo yan ọba si ijọba ibilẹ Ọdẹda, amọ siyalẹnu awọn, wọn to yọ orukọ awọn mẹfa kuro nibẹ ti wọn si forukọ mii-in rọpo ẹ. Ibẹ lo ni wahala ti kọkọ bẹrẹ.


‘’Ninu eto yẹn awọn ogboni wa ninu afọbajẹ amọ ti wọn ko forukọ wọn si i, bi wọn si ṣe maa n ṣe ree, wọn yoo mu mẹta lati Ogboni, mẹta lati Olorogun, mẹta lati ọdọ Oluwo, wọn yoo si mu mẹta ni Apena.

‘’Ilu kọ lẹta si wọn pada pe orukọ tawọn kọ fun yin kọ ni ẹ da pada, nitori awọn to yẹ ki orukọ wọn yẹ ko wa nibẹ ko si nibẹ, ọjọ keji ti wọn kọ lẹta,la gbọ pe wọn fẹẹ ṣe ipade kan ni ẹlẹgun mẹfa, Eko ni mo wa lọjọ naa ti mo ranṣẹ sawọn eeyan mi lati lọ sibẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe nigba ti wọn debẹ ni wọn sọ pe ọba ni wọn fẹẹ yan.

‘’Macgregor  nikan lo wa nibẹ, ipaya ko jẹ ko sọkalẹ ninu mọto,titi ti wọn fi pari, ko sọkalẹ. Ilu ni ile Ogboni ni wọn gbọdọ ti ṣe, awa oludije yooku, wọn ko kọ lẹta si wa, wọn ko pe wa, a ko mọ nnkankan nipa ẹ, gbogbo bi wọn ṣe ṣeto yẹn la ni akọsilẹ ẹ. Wọn ṣa ṣe awuruju lọjọ naa ti wọn sọ pe Macgregor lo wọle’’

Oloye Lawrence tun sọ pe ko si idile to n jọba ninu ilu naa amọ awọn baba wọn lo tẹ ilu naa do nitori nigba ti wọn n bọ lati ifẹ, wọn  lọ si Ila Ọrangun, ọrọ ọba  naa lo da ija silẹ laarin ẹgbọn ati aburo, tawọn kan fi ṣi lati ibẹ lọ si Odo-Ọna ni Ibadan, latibẹ ni wọn gba de inu igbo Ẹgba. Ṣugbọn ki wọn to debẹ abule kan wa ti wọn maa n pe ni ẹlẹgun mẹfa, oun ni wọn fi ṣe ibi ti wọn de si, amọ nigba ti wọn ko dagba soke ni wọn pada lọọ si Alagbaagba.

O ni pupọ ni awọn to di Orile-Ilawọ, Alagbaagba ni wọn wa, ibẹ ni ilu pọ si. Ibẹ ni wọn gba wọnu igbo Ẹgba, to fi jẹ pe Ilahọ jẹ ọkan ninu Ẹgba. Ninu ọrọ Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ti wọn fẹsun kan iyẹn Ọba Oluṣẹgun Macgregor, lo ti sọ pe Oluwa lo yan oun lọba Ilawọ, iṣẹ Eledumare ti ko ṣee tu ni.

O sọ pe kawọn ti wọn n ta ẹjẹ eeyan silẹ nitori ipo ọba atawọn ti wọn n pe orukọ Macregor si ipaniyan lati yee ṣe bẹẹ. Ṣugbọn nnkan to daju ni pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu oun lati gbe Ilawọ goke agba, ki wọn mu gbogbo ikunsinu to wa lọkan wọn kuro patapata, nitori rogbodiyan ki i ran ilu lọwọ, ifasẹyin ati orukọ buruku ni i mu ba ni.

O ni ” Awọn eeyan to mọ emi Ọjọgbọn Macgregor daadaa mọ pe ẹni alaafia ni mi, iṣesi mi gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ ati araalu lasan ko tako alaafia ri, awọn eeyan to mọ mi nilẹ yii ati loke okun si le jẹri si i pe bo ṣe ri gan-an niyẹn’’

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages