Leyin ti Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde, ti so nita gbangba pe ko si awitunwi asan kankan mo, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, loun yoo sise fun gege bi aare orileede yii ti egbe Afenifere naa si ti gba pe okunrin yii lawon n ba lọ, bee gele Gomina tele nipinle Ogun, Amofin Ibikunle Amosun naa ti so pe ileri oun loun duro le lori Oro yii.
Okunrin naa so pe Ida ogorun-un ibo ipinle Ogun, ni yoo je to Bola Ahmed Tinubu fun ipo aare labe egbe oselu APC ati Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC, lodun to n bo
Amosun soro naa nigba to n ba alakoso egbe amuludun omo bibi ipinle Ogun, Kehinde Soaga forojomitoro oro laipe yii. O so pe leyin gbogbo asoye pelu awon elekajeka elegbejegbe, ti won si ti fimo sokan pe Biyi Otegbeye, tegbe oselu ADC, lawon yoo sise fun.
Amosun tun salaye pe oludije yii ni won nireti pe yoo gba awon eeyan ipinle Ogun lowo ijoba to fara ni awon araalu.
O so pe ohun to mu ijoba ipinle Oyo ti won ki i se omo egbe won kede pe Bola Ahmed Tinubu, lawon yoo satileyin fun, bee naa ni awon naa yoo se satileyin fun Otegbeye ti egbe ADC amo sa o, Tinubu ni aare won.
No comments:
Post a Comment