PDP Ogun ni ki wọn ṣewadii awọn to dana sun ọfiisi INEC l' Abeokuta - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 11 November 2022

PDP Ogun ni ki wọn ṣewadii awọn to dana sun ọfiisi INEC l' Abeokuta


 

Ẹgbẹ oṣelu PDP, ipinlẹ Ogun, ti rọ awọn agbofinro lati bẹrẹ iwadii kiakia lori ọfiisi awọn eleto idibo, to wa ni Iyana-Mọṣuari, niluu Abẹokuta, ti wọn lawọn kan dana sun ni oru mọjumọ Tọsidee, ana

 

Ninu atẹjade ti Aṣiwaju Bankọle Akinloye, to jẹ akọwe olupolongo ẹgbẹ naa fi sita, lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni wọn ti fi aidunnu wọn han lori iṣẹlẹ ọhun, gẹgẹ bi eyi ti wọn sọ pe o ba ni lọkan jẹ.

 

Wọn ni bi wọn ṣe dana sun ile ijọba yii jẹ eyi to buru ju to ṣapejuwe pe aabo awọn araalu ipinlẹ Ogun ati ni Abẹokuta ko ṣe gbọkan le , pẹlupẹlu irin itiju ti wọn rin laipẹ yii kaakiri ilu naa.

 

Akọwe olupolongo naa tun ṣalaye pe bi wọn ṣe dana sun ọgba eleto idibo yii,  nibi ti ọpọ kaadi idibo tawọn to forukọ silẹ ti jona di eeru, tawọn dukia mi si bajẹ pẹlu fi han pe ọrọ naa ko le ṣe lẹyin awọn ti wọn ti mọ pe araalu ko gba ti wọn mọ, ti wọn ko si fẹẹ jẹ ko pada wa mọ.

 

Wọn wa rọ gbogbo awọn alaabo ilu lati ma ṣe fi igba-kan-bọkan- ninu lori iṣẹlẹ ọhun, ki wọn ṣe iwadii lati mọ awọn to wa nidii ọrọ naa, ki wọn si fi wọn jofin.

 

Wọn wa ni pẹlu gbogbo nnkan to ṣẹlẹ yii, ireti awọn ni pe ipinlẹ Ogun ko nii pada sẹyin lori iwa janduku ati bi ba nnkan ilu jẹ. Bẹẹ lo ni lẹyin eyi, awọn tun pe Ọmọọba Dapọ Abiọdun nija, lati waa ṣalaye ẹnu ẹ lori iwọde ti wọn ṣe, nibi ti wọn ti lọ ya awọn eeyan lati ipinlẹ mii-in wa da alaafia ipinlẹ yii laamu, ko si fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati le jẹ ki alaafia pada siluu.

 


No comments:

Post a Comment

Pages