Irọ ni wọn pa, Olu Ilaro ko ni ki Ọtẹgbẹyẹ jawọ fun ipo gomina-OGWA - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 10 November 2022

Irọ ni wọn pa, Olu Ilaro ko ni ki Ọtẹgbẹyẹ jawọ fun ipo gomina-OGWA


 

Ẹgbẹ kan ta a mọ si  Ogun West Grassroots Alliance, OGWA,  ti sọ pe ko si ootọ Kankan ninu ahesọ ọrọ ti wọn n gbe jade pe Olu tilu Ilaro ati olori Ọba ilẹ Yewa, Ọba Kẹhinde Olugbenle, ti paṣẹ pe Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, to tun jẹ oludije kan ṣoṣo to wa lati Yewa- Awori, fi erongba ati dije ẹ silẹ, wọn ni ko si nnkan to jọ.

 

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, lẹyin ipade wọn to waye ni Ọmọọba Bọlaji Adeniji, to jẹ alakoso ẹgbẹ ọhun ti sọ pe irọ patapata gba a ni, kawọn araalu ma ṣe tẹti siru ọrọ bẹẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni gbogbo eeyan lo mọ pe oludije gomina ADC, nikan lo jẹ ọmọ Yewa-Awori, ninu idije ọhun, ti wọn si fi tayọtayọ ki kaabọ nigba to wa ki Olu Ilaro

 

Adeniji tun sọ pe “ Ki i ṣe pe wọn kan ki Biyi Otegbẹyẹ, kaabọ lasan bẹẹ naa ni Kabiyesi atawọn Oloye ẹ tun fi tọwọtọwọ gba a, ti wọn si tun sure ori-ade fun un nipa erongba ẹ lati le ṣe aṣeyọri''

 

Wọn ni iyalẹnu lo wa jẹ fawọn pe oludije ti wọn sọ pe wọn ko pe dsi afin ṣe wa dẹni to n gba ire lẹnu ọba. Ẹgbẹ OWGA, wa lo anfaani naa lati dupẹ lọwọ Ori-ade atawọn ọba alaye yooku nilẹ Yewa ati Awori.

O sọ pe, ''  Adupẹ gidi lọwọ awọn Kabiyesi wa fun ẹmi ọgbọn ti wọn n lo lati fi ṣatilẹyin ohun tawọn eeyan n fẹ. Eyi fihan pe ko si ainiaini kankan nibẹ awọn ọba ilẹ Yewa ti gba lati fimọ sọkan fa gomina kalẹ lati ọdọ wọn,, fun ti aṣeyọri anfaani nla to yọ yii.

Ẹgbẹ yii wa rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹti si awọn ahesọ, nitori awọn mọ pe akoko ta a wa yii oriṣiriṣi nnkan ni yoo ma jẹyọ, ṣugbọn eyi to ṣe pataki ni pe ki wọn ma di okodoro ọrọ mu.

OWGA, tun wa gboriyin fun Olu  Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle,  fun adura ati ire ti su fun oludije gomina fẹgbẹ ADC, Agbẹjọro Biyi Otẹgbẹyẹ.

Wọn wa ṣapejuwe ẹgbẹ naa, nilẹ Yewa-Awori, gẹgẹ eyi ti ẹlẹgbẹjẹgbẹ ọmọ ilu wa ninu ti wọn si wa fun idagbasoke ọrọ aje ati oṣelu to kan gbogbo ọmọ bibi Ogun West.

Wọn wa lo akoko naa lati ke si gbogbo ọmọ bibi Yewa-Awori, lati fọwọsowọpọ pẹlu Biyi Ọtẹgbẹyẹ lati jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, ọdun 2023.

“Inu wa dun gbogbo awọn eeyan nilẹ Ẹgba ati Ijẹbu, ni wọn ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Ọtẹgbẹyẹ, lati jawe olubori ninu ibo to n bọ naa''

 

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages