Ibẹrubojo pe wọn ko le wọle ẹlẹẹkeji lo mu wọn dana sun ileeṣẹ INEC- ADC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 10 November 2022

Ibẹrubojo pe wọn ko le wọle ẹlẹẹkeji lo mu wọn dana sun ileeṣẹ INEC- ADC


Ẹgbẹ oṣelu  African Democratic Congress (ADC) tipinlẹ Ogun, ti bu ẹnu atẹ awọn kan ti wọn sọ pe ibẹrubojo n de bawọn lati wọle ibo ẹlẹẹkeji, gẹgẹ bi awọn to wa nidii bi ileeṣẹ INEC, ṣe jona l’ Ọjọbọ, Tọsidee.

 

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, eyi ti akọwe olupolongo ẹgbẹ ọhun fọwọ si, ni wọn sọ pe ko si tabi ṣugbọn Kankan nipa iṣẹlẹ to waye ọhun, bi ko ṣe awọn ti ireti wọn ti pin lori pe wọn ko ni atilẹyin awọn araalu mọ, ni wọn ṣe dana sun ọfiisi ni erongba lati dana sun kaadi idibo PVC, awọn to ṣẹṣẹ forukọ silẹ.

Wọn sọ pe ‘’ A tako gbogbo ọgbọn ete oṣelu tawọn kan lo ti wọn fi lo awọn ti wọn dana sun ọfiisi nla bi ti INEC. Eyi fi han pe awọn ti wọn padanu lati mu ilero wọn ṣẹ fawọn araalu lakooko ipolongo wọn, ti wọn ko si le ṣeto ibo ti yoo mu alaafia wa, ni wọn ṣiṣẹ naa lati le jẹ ko ṣoro fawọn oludobo ti wọn ṣẹṣẹ forukọ silẹ lati dije ninu ibo to n bọ lọna.’’

 

Ẹgbẹ oṣelu ADC wa ke si awọn agbofinro ati ọga agba pata fawọn ọlọpaa lati ṣe iwadii, ki wọn si mu awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi naa atawọn to ṣe onigbọwọ wọn.

 


No comments:

Post a Comment

Pages