Àpèjẹ́ ADC, Dide lati yọ yipada di Dide lati jawe olubori- Ọtẹgbẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 9 November 2022

Àpèjẹ́ ADC, Dide lati yọ yipada di Dide lati jawe olubori- Ọtẹgbẹyẹ


Wọle Elegbede

 

Gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ pe àpèjẹ́ ẹgbẹ oṣelu Afican Democratic Congress, iyẹn ADC ni ‘Didelati yọ ti wa yi pada bayii lati di ‘Dide lati jawe olubori, ko si si idi mii-in bi ko ṣe pe lati ji awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu naa ati araalu fun aṣeyọri ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Bẹẹ lo si n paroko ranṣẹ si Gomina Dapọ Abiọdun, igbakeji ẹ atawọn oloṣelu ti wọn jọ ṣiṣẹ papọ lati maa palẹ ẹru wọn mọ, ko to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un, ọdun to n bọ.

 

Bo tilẹ jẹ pe bi awada lo si n jẹ loju awọn to wa nidii agbara bẹẹ naa ni yoo si ri titi ti awọn ọmọ ipinlẹ Ogun yoo fi lo agbara ibo wọn lati gbakoso, ti ọrọ inu Bibeli to sọ pe nigba ti ogun Jẹriko wo, bi ere ọmọde lo ri bẹẹ naa ni yoo jẹ fun Dapọ Abiọdun.

 

Ju ti tẹlẹ lọ, ni ẹgbẹ oṣelu ADC, ti wa ni imurasilẹ lati jawe olubori ibo Gomina, ẹgbẹ yii ti wa digbi, lati jẹ kawọn eeyan mọ pe awọn ko fọrọ naa ṣere lati gba akoso ipinlẹ naa. Nitori ifarajin,iṣẹ takuntakun, awọn ọmọ ẹgbẹ si ti pinnu lati mu ijakulẹ ba ijọba to wa lode.

 

Apẹẹrẹ rere lo waye, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii, nigba Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, ti gbgogbo eeyan mọ si BOT, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, faye silẹ lati yii apejẹ ADC pada.

 

Ninu ọrọ to sọ, o ni, ‘’ O da mi loju pe gbogbo yin ni ẹ ti maa gbọ apejẹ wa Dide lati yọ, o ti wa yi pada si Dide lati jawe olubori.O ni idi fun eleyii, mo ro pe a fa a yọ ninu Nehemiah, bẹẹ ni, o ṣe pataki lati gbadura, bẹẹ lo tun ṣe pataki lati ṣiṣẹ, nitori idi eyi ni a ko gbọdọ dakẹ lori Dide lati tan. A ni lati pe akiyesi wa sawọn nnkankan,a ko wa  lati yọ lasan bi ko ṣe lati jawe olubori’’  

 

 

Aṣaaju rere ni Ọtẹgbẹyẹ,ti Ọlọrun fun ni imọ to peye ninu ibanisọrọ nidii oṣelu, gẹgẹ bi ẹni to kawe gboye yunifasiti nigba to wa lọmọ ogun ọdun,  o ṣakitiyan lati kọ nipa imọ ibaraẹnisọ nileewe yunifasiti ṣugbọn ti Ọlọrun pese aye idojutofo silẹ fun un, nibi to ti tun igbe aye ọpọ eeyan ṣe.

 

Igba kan, o sọ fawọn akọroyin ẹ lakooko ti wọn ṣe ipade ninu oṣu kẹjọ ọdun yii pe, oun jade lati jawe olubori ki i ṣe fun okiki lasan. Iyalẹnu lo jẹ pe alatako ẹ si n fojoojumọ gbo bi aja, nitori bi Ọlọrun ṣe fi ọna iyanu gbe e dide lati dupo gomina.

 

Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ADC, ko tii bẹrẹ ipolongo wọn amọ sibẹ ibẹru ẹgbẹ oṣelu ọhun ni ipinlẹsẹ ọgbọn ati oye. Ṣugbọn awọn alatako yii kuna lati lo ọgbọn ki alaafia le jọba fun ipolongo. Kaka bẹẹ, wọn bẹrẹ si ni lo idunkoko iku fawọn eeyan fun ibo to n bọ naa.

 

Apejẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni lati jawe olubori, eyi ti Ọlọrun ti pari ẹ, lati gba agbara ati akoso ipinlẹ Ogun le Ọtẹgbẹyẹ lọwọ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages